Lara fẹnsi ile tawọn mẹrin kan duro si lọkọ elepo kan tẹ wọn pa si l’Abẹokuta   

Faith Adebọla, Abẹokuta

Eeyan mẹrin ni ajọ ẹṣọ oju popo ilẹ wa fidi rẹ mulẹ pe wọn ku nifọna-fọnṣu, nigba ti ọkọ tanka agbepo kan ti nọmba rẹ jẹ T-15321LA ati ọkọ ayọkẹlẹ meji, BMW, ti nọmba tiẹ jẹ TTD421CX ati jiipu Nissan kan ti ko ni nọmba fori sọra wọn lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹta yii, ni agbegbe Lafẹnwa, niluu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun.

Gẹgẹ bi Alukoro ẹṣọ oju popo (FRSC,) nipinlẹ Ogun, Abilekọ Florence Okpe ṣe ṣalaye ọrọ naa fun Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa, (NAN), o ni ere asaju ti ọkọ tanka naa n sa lo fa ijamba ọhun. O ṣalaye pe nibi ti ọkọ tanka naa ti fẹẹ tọọnu nibi ọna olobiripo to wa ni Lafẹnwa, lo ti sọ lu awọn mọto meji naa, to si tu lọọ rọ lu fẹnsi ile kan. Niṣe lo mu awọn eeyan mẹrin ti wọn duro sibi fẹnsi ọhun gun, to si pa wọn nipakupa.

Awọn panapana atawọn eeyan ti wọn wa nitosi la gbọ pe wọn sare da epo ti tanka naa gbe, ṣugbọn ti diẹ ti da silẹ lasiko ijamba naa sinu ọkọ mi-in.

Okpe ni awọn mọlẹbi awọn to ku nibi iṣẹlẹ naa ti waa gbe oku awọn eeyan wọn lọ.

Ọga agba ẹṣọ oju popo, Ahmed Umar, ti fi aidunnu rẹ han si iṣẹlẹ buruku naa. O bu ẹnu atẹ lu bi awọn ọkọ nla yii ṣe maa n wa mọto niwakuwa loju popo lai bikita, ti wọn ko si ni i ro ti awọn ero yooku ti wọn jọ n lo oju ọna naa mọ tiwọn.

Bakan naa lo kẹdun pẹlu mọlẹbi awọn ti wọn padanu ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ naa.

 

Leave a Reply