Lasiko ayajọ aadọta ọdun lori oye, Ọba Adeyẹmi fun Ajobiewe ni jiipu tuntun

Dada Ajikanje

Beeyan gun ẹṣin ninu kunrin Apẹsa ti wọn n pe ni Sulaiman Ayilara Ajobiewe, tọhun ko ni i kọsẹ. Eyi ko sẹyin bi Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi ṣe fi ẹbun ọkọ jiipu ta ọkunrin naa lọrẹ lasiko ti ọba alade naa n ṣe ayẹyẹ aadọta ọdun to ti gori itẹ awọn baba rẹ.

Ọkunrin yii ko le pa idunnu rẹ mọra pẹlu bo ṣe mu oriki Alaafin bọnu, to bẹrẹ si i ki i ni mẹsan-an mẹwaa fun oore to ṣe fun un yii.

Bi baba naa ṣe tobi to lo ṣe dọbalẹ gbalaja, to n yiraa nilẹ, to si n dupẹ lọwọ Ọba Adeyẹmi.

Ki i ṣe oun nikan ni Iku Babayeye ta lọrẹ o. Ọpọ eeyan lo gba ẹbun loriṣiiriṣii, bẹẹ lo si tun fi oye da awọn eeyan lọla.

Leave a Reply