Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Awọn ara ṣọọṣi CAC to wa ni Gudugbẹ Alagbọn, ni Waasinmi, nijọba ibilẹ Ewekoro, ipinlẹ Ogun, ko le gbagbe Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja yii, nigba ti wọn n ṣe iṣọ oru lọwọ, ti awọn janduku mẹfa wọnu ṣọọṣi pẹlu nnkan ija, ti wọn lu awọn ara ṣọọṣi naa bii ki wọn ku, ti wọn ja wọn lole, ti wọn si tun ji ẹni kan gbe sa lọ ninu wọn.
Mẹfa lawọn adigunjale ajinigbe naa gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun ṣe wi, ṣugbọn marun-un lọwọ ṣi ba, awọn naa si ni:Ababakar Ibrahim, Sulaiman Yusuf, Umar Aliu,Ismail Yusuf ati Yinusa Musa.
O ṣalaye pe olobo ta awọn ọlọpaa pe awọn ole ti ya wọ ṣọọṣi naa ni nnkan bii aago kan aabọ oru, ati pe niṣe ni wọn n lu awọn eeyan to n sin Ọlọrun wọn jẹẹjẹ, koda, wọn gba owo atawọn nnkan mi-in ti wọn ba lọwọ awọn olujọsin naa. Paripari rẹ ni pe niṣe ni wọn tun ji obinrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Mojisọla Atọlagbe, sa wọgbo lọ.
Eyi lo mu awọn ọlọpaa Ewekoro naa wọnu igbo ti awọn janduku naa sa wọ, wọn fọ gbogbo ẹ yi ka, wọn si pada ri marun-un mu ninu awọn mẹfa naa. Koda, awọn eeyan ti wọn fiya jẹ ninu ṣọọṣi jẹrii si i pe awọn to ṣe awọn ni jamba ọhun lawọn ọlọpaa wa jade yẹn.
Awọn nnkan ija tawọn ọlọpaa ba lara awọn janduku naa ni: ada kan, awọn irin ṣooro meji ti wọn mu bii ida pẹlu oriṣiiriṣii oogun ibilẹ ti wọn fi n ṣọṣẹ.
Bọwọ ṣe tẹ wọn yii naa ni awọn agbofinro ṣi n wa ẹni kẹfa wọn. CP Edward Ajogun ti i ṣe ọga wọn nipinlẹ yii si ti paṣẹ pe ki wọn maa rin kaakiri awọn agbegbe, kawọn oniṣẹ ibi le mọ pe ọlọpaa ṣi wa niluu, ki wọn le ṣiwọ aburu ṣiṣe.
In this State, the number one things people are suffering for is the BAD ROAD. Any Government that will rule this State must have it in mind that we are lacking good road accross the state.
Then concerning the Fulani Herdsmen; they should kill them silently Because they are not ready to change. And morever, they’re harming the peace of the citizens of this State. Let them be as a scape goat for others. Thank you.
The news is not complete, what about the kidnap lady?