Lasiko igbele Korona ni Baba Mariam ki ọmọ ẹ mọlẹ, o ba a lo pọ karakara

Florence Babaṣọla

Obinrin kan, Basirat Ismail, ti sọ pe lasiko igbele Koronafairọọsi to waye lọdun to kọja ni ọkọ oun atijọ, Kazeem Ọlapade, ti ki akọbi oun mọlẹ, to si bẹrẹ si i ba a sun ko too di pe aṣiri tu.

Nigba ti obinrin yii fara han nileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin ati ọmọ wẹwẹ nipinlẹ Ọṣun, lo ṣalaye pe ọdun 2006 loun ati Ọlapade fẹra awọn bii lọkọ-laya, ṣugbọn nigba ti ede-aiyede kan ṣẹlẹ lọdun 2009 lawọn tu ka, ti oun si ko awọn ọmọbinrin mejeeji toun bi fun un; Mariam ati aburo rẹ, silẹ sọdọ ọkọ.

O ni aburo Mariam lo sọ fun oun laipẹ yii pe baba awọn huwa aitọ yii si Mariam, ẹni to ti di ọmọ ọdun mẹrinla bayii, lasiko igbele Korona.

A gbọ pe ọdọ awọn ajọ Sifu Difẹnsi niluu Oṣogbo ni wọn kọkọ ko ẹjọ naa lọ ki wọn too gbe e lọ si ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran nileeṣẹ ọlọpaa, SCID.

Ajọ kan ti ki i ṣe tijọba, Mọnsurat Foundation, la gbọ pe o lọọ fi ọrọ naa to ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin atawọn ọmọ wẹwẹ nipinlẹ Ọṣun leti, ti awọn yẹn si lọọ fi pampẹ ọba gbe baba alailojuuti naa.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun, Kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin ati ọmọ wẹwẹ, Barisita Olubukọla Ọlabọọpo, ẹni ti Iyaafin Dorcas Lawrence ṣoju fun, ṣalaye pe bo tilẹ jẹ pe baba naa ti de kootu, ti wọn si ti lọọ fi i pamọ si ọgba ẹwọn ilu Ileṣa bayii, sibẹ, awọn yoo ba ọrọ naa debi to lapẹrẹ, awọn ko ni i jawọ nibẹ titi ti idajọ ododo yoo fi fẹsẹ mulẹ lati le jẹ ẹkọ fun ẹnikẹni to ba tun fẹẹ ṣan aṣọ iru rẹ ṣoro.

Leave a Reply