Lasiko tawọn agbẹ n ṣiṣẹ ninu oko lawọn afurasi Fulani ji wọn gbe ni Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Niṣe lawọn afurasi Fulani darandaran ya bo awọn agbẹ kan ninu oko odo ẹja wọn niluu Oko-Irese, nijọba ibilẹ Irẹpọdun, nipinlẹ Kwara, ti wọn si ji awọn agbẹ naa gbe lọ lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii.

Iroyin to tẹ ALAROYE lọwọ ni pe lakooko ti awọn agbẹ ọhun ti wọn pọ niye n ṣiṣẹ lọwọ ninu oko wọn ni awọn afurasi Fulani darandaran ya bo wọn, ti wọn si ji gbogbo wọn gbe lọ.

Awọn olugbe iluu naa ti waa gbara ta, wọn si bu ẹnu atẹ lu ijọba ipinlẹ Kwara pe lati ọjọ Aje ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ, ijọba ko gbe igbesẹ kankan lati doola ẹmi awọn agbẹ naa. Ti wọn si ni ipinlẹ Kwara ti di ẹrujẹjẹ bayii tori pe ko si aabo mọ rara, bi awọn ajinigbe ṣe n gbe ara ile ni wọn tun n gbe ara oko, awọn arinrin-ajo naa ko si mori bọ lọwọ wọn.

Wọn ti waa rọ ijọba Kwara lati tete gbe igbeṣẹ akin, ki wọn doola ẹmi awọn ti wọn ji gbe, ki ijọba si pese aabo to peye fun gbogbo olugbe ipinlẹ naa patapata.

Leave a Reply