Lasiko tawọn eleyii n digunjale lọwọ lawọn agbofinro ko wọn n’Ikẹja

Faith Adebọla, Eko
Akolo ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n tọpinpin iwa ọdaran ati idigunle l’Ekoo lawọn gende mẹta yii Azeez Adeleke, Solomon Odiya ati Usman Mohammed, wa bayii. Ibi ti wọn ti n fibọn jale loju popo lagbegbe Mobọlaji Johnson, n’Ikẹja, ni wọn ti fi panpẹ ofin gbe wọn.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mọkanla ku iṣẹju mẹẹẹdogun ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa yii, lọwọ ba awọn afurasi ọdaran mẹtẹẹta. Ẹnikan ti wọn ṣẹṣẹ ja lole, ti wọn gba dukia ẹ nirona, lo ta awọn ọlọpaa ti wọn n ṣe patiroolu laduugbo naa lolobo.
Bawọn agbofinro naa ṣe yọ si wọn, ere buruku ni wọn lawọn jagunlabi mẹtẹẹta gbe da si i, ṣugbọn wọn le wọn ba ki wọn too ṣẹ kọna.
Lara nnkan ti wọn ba lọwọ wọn ni foonu Tecno kan ti wọn ṣẹṣẹ ja gba, ọbẹ aṣooro oloju meji kan, ẹgbẹrun marun-un o le irinwo Naira (N5,400).
Ninu iwadii tawọn ọlọpaa ṣe, wọn lawọn alọ-kolohun-kigbe ẹda yii ti pẹ lẹnu iṣẹ laabi wọn, wọn ti n figba kan ja awọn eeyan lole lagbegbe kan naa, wọn ni wọn lọ, wọn tun pada wa ni, ki ọwọ too ba wọn lọtẹ yii.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Abiọdun Alabi, ti ni kawọn ọtẹlẹmuyẹ tubọ ṣiṣẹ iwadii wọn pari, ki wọn le foju awọn afurasi yii bale-ẹjọ, ki wọn le gba sẹria to tọ si wọn.
O ni ko saaye fawọn janduku ati ọdaran l’Ekoo, tori awọn maa mu wọn debi ti wọn aa ti kan idin ninu iyọ tọwọ ba ba wọn.

Leave a Reply