Lasiko ti Ayọmide ati Abiọdun fẹẹ lọọ digunjale ni wọn bọ sọwọ ọlọpaa n’Ijẹbu

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Odukọya Ayọmide ati Abiọdun Oyenuga ni awọn mejeeji ti ẹ n wo yii, ẹni ọdun mejilelọgbọn ni wọn. Oju ọna marosẹ Awa Ijẹbu s’Ijẹbu-Ode lawọn ọlọpaa ti mu wọn lọsẹ to kọja yii pẹlu ibọn lasiko ti wọn n lọ soko ole kan ni Awa-Ijẹbu.

Ẹlẹṣẹ n sa nigba ti ẹnikan ko le e lọrọ wọn gan-an jọ gẹgẹ bi alaye ti Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe nipa wọn. O ni lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹjọ, ni DPO Awa-Ijẹbu, CSP Adewalẹhinmi Joseph, n wọde loju ọna naa pẹlu awọn ikọ rẹ, n lawọn afurasi meji yii ti wọn wa lori ọkada ba sare bọ silẹ nigba ti wọn ri awọn ọlọpaa, ni wọn ba n sa lọ.

Bi wọn ṣe n sa lọ ni awọn ọlọpaa naa bẹrẹ si i le wọn, nigbẹyin, wọn ri Odukọya Ayọmide mu. Ibọn ilewọ oloju meji ni wọn ba lara ẹ, oun lo si jẹwọ fun wọn pe oun ati Abiọdun fẹẹ lọọ jale ni, ati pe Abiọdun gan-an lo ni iṣẹ naa. O ni Abiọdun lo pe oun lati Ijẹbu-Ode pe kawọn jọ lọọ jale ọhun pẹlu ibọn ti wọn ba lọwọ oun yẹn.

Ọjọ kẹta tọwọ ba Ayọmide ni wọn ri Abiọdun naa mu, Ṣagamu ni wọn ti ri oun mu lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹjọ. Wọn ti ko awọn mejeeji lọ sọdọ awọn SARS fun itẹsiwaju itọpinpin gẹgẹ bi CP Edward Ajogun ṣe paṣẹ.

Leave a Reply