Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa yii, ni iṣẹlẹ abami kan ṣẹlẹ lagbegbe Adéta, niluu Ilọrin, nibi ti Abilekọ Sikirat Jamiu, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta, ti ko sodo lasiko to fẹẹ fa omi, oku ẹ ni wọn gbe jade ninu kanga ọhun.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ panapana ni Kwara, Hassan Hakeem Adekunle, fi sita niluu Ilọrin, eyi to tẹ ALAROYE lọwọ lo ti salaye pe ileesẹ panapana ti yọ arabinrin kan, Abilekọ Sikirat Jamiu, to n gbe ni agboole Agúnkọ, Adéta, niluu Ilọrin, ninu kanga kan to ko si. Lasiko to fẹẹ pọnmi kanga lagboole Oníkókó, lẹsẹ rẹ kan yẹ, eyi to ṣokunfa bo se takiti sinu odo ọhun.
Adekunle, ni nnkan bii aago meje ku diẹ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn gba ipe pajawiri lati ọdọ Mohammed Jamiu, to jẹ alaamuleti Sikirat, pe ẹni kan ti ko sodo lagbegbe Adéta, eyi lo mu ki ileesẹ panapana tete sare lọ sibi iṣẹlẹ ọhun. Ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe obinrin naa ti mumi yo, to si ti ku ki awọn too debẹ. O ni awọn yọ oku rẹ jade, ti awn si gbe e fun Aafaa AbdulGaniyu Àkùkọ, to jẹ ọkan lara mọlẹbi oloogbe. Bẹẹ lawọn ọlọpaa lati Agọ Adéwọlé, naa wa nibẹ.
Ọga agba ajọ panapana ni Kwara, Ọmọọba Falade John Olumuyiwa, fi ibanujẹ ọkan rẹ han lori iṣẹlẹ naa, o rọ gbogbo olugbe Kwara, ki lati maa ṣọra gidigidi lori gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe lojoojumọ, ki wọn si yago fun riran awọn ọmọ tọjọ ori wọn kere lọ sibi kanga lati maa lọọ fa omi, o si kẹdun pẹlu mọlẹbi oloogbe.