Lasiko ti Waheed n toko ole bọ lo ko sọwọ ọlọpaa l’Ọta

Gbenga Amos, Abeokuta
Bi Waheed Ijiyẹmi ṣe mura tan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin yii, niṣe lo bẹ sori ọkada rẹ, ko si sẹni to fura si i pe iṣẹẹbi kan lo fẹẹ lọ ṣe, afi ti ọkada rẹ ti ko ni nọmba.
Ọkada yii lawọn ọlọpaa lati ẹka teṣan wọn to wa ni Onipanu, lagbegbe Ọta, nijọba ibilẹ Ado-Odo, nipinlẹ Ogun kiyesi, nigba ti CSP Bamidele Job ati awọn ọmọọṣẹ rẹ n ṣe patiroolu agbegbe naa kiri lọjọ Tusidee ọhun.
Bi afurasi ọdaran yii ṣe foju kan awọn ọlọpaa lo fura pe wọn ti ri i pe ọkada oun ko ni nọmba, koju ma ribi, ẹsẹ loogun ẹ, niṣe lo bẹ silẹ lori ọkada naa, lo ba ki ere buruku mọlẹ, o fẹẹ na papa bora.
Ṣugbọn awọn ọlọpaa gba fi ya a, gẹgẹ bi atẹjade ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, fi ṣọwọ s’ALAROYE ṣe wi, wọn le e titi ti wọn fi ri i mu, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe e.
Ibẹ laṣiiri ti tu pe ki i ṣe ọkada to niwee ati nọmba nikan ni Waheed tori ẹ ki ere mọlẹ, oriṣiiriṣii nnkan ija oloro ni wọn ba lara ẹ. Ibọn oyinbo pompo kan, katiriiji ọta ibọn ti wọn o ti i yin mẹwaa, ọbẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ, inu apo kekere to gbe kọrun lo ko wọn si.
Nigba ti wọn bi i leere nnkan to fẹẹ fi wọn ṣe, o jẹwọ pe adigunjale loun, opureṣan kan loun n lọ lasiko ọdun Ajinde, oun o si mọ p’oun maa pade awọn ọlọpaa lọna.
CP Lanre Bankọle, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ni ki wọn ṣewadii to lọọrin lori ọrọ rẹ lẹka to n ri si itọpinpin iwa ọdaran bii eyi, ti wọn ba si ti pari iwadii, afurasi ọdaran naa yoo lọọ ṣalaye ara ẹ niwaju adajọ.

Leave a Reply