Lasiko ti wọn n fẹhonu han nitori SARS, awọn ọdọ gbe posi lorukọ Buhari l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Lati Freedom Park, to wa ni Old Garage, niluu Oṣogbo, lawọn ọdọ naa ti bẹrẹ ifẹhonu han wọọrọwọ, nigba ti wọn de orita Ọlaiya, wọn duro, bẹẹ ni wọn ko faaye gba irinkerindo ọkọ tabi ọlọkada kankan.

Bi wọn ṣe n kọ oniruuru orin, ni wọn n jo pẹlu ẹrọ amohun-bu-gbamu nla kan ti wọn gbe soju titi.

Ohun ti wọn kọ si ara akọle ti wọn gbe lọwọ ni pe ṣe ni kijọba fiya jẹ gbogbo ọmọ ikọ SARS to ti lọwọ ninu iku ọdọ kan tabi omi-in lorileede yii.

Bo ṣe di nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ni wọn gbe pako ọhun de, posi ni. Aworan Aarẹ Buhari ni wọn lẹ mọ ọn lara kaakiri.

Bẹẹ ni wọn bẹrẹ orin aro, wọn ni ki lo de ti awọn ọlọpaa ko gbọdọ foju kan ọdọkunrin to ba rẹwa, to mu foonu gidi lọwọ tabi to n lo mọto gidi, to waa jẹ pe pipa ni wọn n pa wọn bii ẹwurẹ.

Awọn ọdọ naa ni asiko niyi funjọba orileede yii lati mọ pe bi wọn ṣe fẹẹ jẹun ọmọ lawọn obi tawọn naa fẹẹ jẹun ọmọ, ki wọn dẹkun pipa awọn nipakupa.

Wọn gbe posi naa lati Ọlaiya lọ si Okefia, kọja lọ si Old Garage, ki wọn tun too dari si orita Ọlaiya.

Leave a Reply