Lasiko yii, a ko fẹ Sunday Igboho niluu Iṣẹyin –Asẹyin

Asẹyin tilu Isẹyin, Ọba AbduganiyY Salau, ti kilọ fun ọkan ninu awọn ajijagbara ilẹ Yoruba, Sunday Igboho atawọn ẹgbẹ rẹ ti wọn n ja fun Orileede Oodua pe wọn ko gbọdọ gbe ipolongo wọn de ilu Isẹyin lasiko yii.

Ninu ọrọ ti Kabiyesi ba akọroyin iwe iroyin Punch sọ lo ti sọrọ naa lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ọba alaye naa ni bi nnkan ṣe ri niluu naa bayii ko faaye gba iru iwọde bẹẹ, o ni o le di ija igboro ti yoo si tun da wahala mi-in silẹ.

Eyi ko sẹyin bi awọn aṣọbode ṣe pa eeyan marun-un nigba ti wọn n le awọn onifayawọ lọ lọsẹ to kọja.

Leave a Reply

%d bloggers like this: