LASTMA mu awọn to maa n ja ero ọkọ lole pẹlu POS ti wọn fi n gbowo lọwọ wọn

Monisọla Saka

Ọwọ ṣinkun awọn ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko, LASTMA, ti tẹ awọn afurasi meji kan ti wọn maa n ja awọn eeyan lole ninu ọkọ ero, ti wọn yoo si lọọ ja awọn eeyan ọhun ju sibi ti wọn ko mọ lẹyin ti wọn ba ṣọṣẹ tan. Awọn oniṣẹ ibi ti pupọ awọn eeyan mọ si wan ṣansi (one chance), ti wọn n da awọn olugbe Ikate, lagbegbe Lekki-Ajah, nipinlẹ Eko, laamu yii, ni omi gbẹ lẹyin ẹja wọn, ti wọn si ṣe bẹẹ ko sọwọ awọneeyan ọhun.

Agbẹnusọ ajọ naa, Taofiq Adebayọ, sọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, pe ọga agba ajọ LASTMA, Bọlaji Ọrẹagba, ṣalaye pe awọn ikọ ti wọn n yide kiri ti wọn si tun n dari awọn ọkọ lati le dena sun-kẹrẹ -fa-kẹrẹ ọkọ lagbegbe naa ni wọn ri awọn afurasi ọhun mu.

O ni, “Lasiko tawọn eeyan wa wa lẹnu iṣẹ ni wọn n gbọ ariwo ‘ole, ole, ẹ gba wa o’ ninu mọto ero T4, ti wọn ko kun lọda ipinlẹ Eko, pẹlu nọmba idanimọ mọto AAA 750 XX. Bi wọn ṣe n gbiyanju ati da awakọ naa duro lo tẹna mọ ọn, lẹyẹ-o-sọka lawọn oṣiṣẹ LASTMA ọhun si fi mọto ti wọn fi maa n yide kiri gba ya a, titi ti wọn fi le e ba lagbegbe Ikate, nibi ti ọkọ jiipu Pathfinder kan ti ẹlẹyinju aanu kan wa ti ba wọn dina mọ ọn, airibi gba kọja loju ọjọ yii lo jẹ ko rọrun fawọn ajọ LASTMA lati tete ribi yi wọn ka.

“Nigba tọwọ tẹ meji ninu wọn, awọn meji yooku ti wọn gbe ẹrọ pelebe POS, ti wọn fi n gbowo jade ni banki awọn to ba ko si panpẹ wọn ninu ọkọ ero T4 yii kan lugbo ni tiwọn ni.

Awọn ikọ ọlọpaa ayaraṣaṣa RRS, ti wọn wa lẹnu iṣẹ wọn nibi ti wọn maa n paaki ọkọ wọn si lagbegbe Chisco, Opopona Lekki si Ajah, nipinlẹ Eko, ni wọn fa awọn afurasi mejeeji tọwọ ba ati mọto ti ko lọda ti wọn fi n ṣiṣẹ ibi kiri le lọwọ. Lẹyin naa ni wọn ṣẹṣẹ waa ko wọn lọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Ilasan, fun iwadii to peye”.

Ọgbẹni Ọrẹagba gba awọn eeyan agbegbe naa atawọn olugbe ipinlẹ Eko lapapọ nimọran lati ri i daju pe inu garaaji ni wọn ti n wọkọ, ki wọn ma si ṣe figba kankan tura silẹ, ki wọn maa wa ni ojufo nigbakuugba ti wọn ba n wọkọ ero kaakiri ipinlẹ Eko.

Leave a Reply