LASTMA, ọlọpaa ti pada sigboro, ni wọn ba ni kawọn onimọto ṣọra wọn l’Ekoo

Aderohunmu Kazeem

Ni bayii ti awọn LASTMA tun ti bọ soju titi, ileeṣẹ to n ri si irinna ọkọ l’Ekoo ti kilọ fawọn onimọto ki wọn ṣe pẹlẹpẹlẹ pẹlu ofin eto irinna, ki wọn ma baa foju wina ofin.

Alaga ẹṣọ naa, Ọlayinka Ẹgbẹyẹmi, ti sọ pe, “Eyi ni lati sọ fun gbogbo eeyan ti wọn n lo mọto l’Ekoo pe ki wọn yẹra fun gbogbo ohun to le mu wọn lu ofin irinna, paapaa awọn to maa n gba ojuna BRT, ọna yẹn ko si fun ọkọ mi-in bi ko ṣe mọtọ akero ijọba. Ohun to buru ni bi awọn eeyan ṣe maa n tapa si ofin irinna, ni bayii ti ohun gbogbo ti wa bo ṣe yẹ ko wa, gbogbo awọn ti wọn n ṣe bo ṣe wu wọn gbọdọ tete tọwọ ọmọ wọn bọṣọ bayii.

Bakan naa lo kilọ fawọn ọlọkada ki wọn ma ṣe kọja aaye wọn, paapaa lori awọn ibi ti ijọba sọ pe ki wọn ma gbe ọkada wọn de laarin ilu l’Ekoo.

Ana ọjọ Aje, Mọnde, lawọn eeyan ipinlẹ Eko bẹrẹ si i ri ọlọpaa atawọn oṣiṣẹ LASTMA to n dari lilọ-bibọ ọkọ pada loju popo.

Ni kete ti rogbodiyan SARS ti bẹ silẹ ni titi Eko ti da paroparo, tawọn ẹṣọ agbofinro lọlọkan-ọ-jọkan yii ti ba ẹsẹ wọn sọrọ, ti kaluku si ti gba ile ẹ jokoo si.

Ni bayii, ti wahala ọhun ti rọlẹ, kaakiri ni awọn eeyan ti n ri awọn LASTMA loju titi, ti wọn n dari ọkọ, ti wọlu-kọọlu to gba gbogbo igboro kan lọsẹ to kọja si ti n yatọ bayii.

ALAROYE gbọ pe awọn ọlọpaa ti wọn ti pada soju titi yii ko ṣai ran ọkunrin ọlọkada kan ti tirela kọ lu lori biriiji Ọtẹdọla, lọwọ ni Ọjọ Aje ọsẹ yii. Bakan naa lawọn eeyan ti n sọ pe bi awọn ọlọpaa ṣe n lọ kaakiri yii yoo mu adinku ba bi awọn janduku kan ṣe n ja baagi, ti wọn n kọ lu awọn eeyan kaakiri Eko, nigba ti ko si ẹṣọ agbofinro to le ṣe kai si wọn.

Leave a Reply