L’Atan-Ọta, ọwọ ba ọmọ ẹgbẹ okunkun mẹrin nibi ti wọn ti n yinbọn sira wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ija agba ti ki i yee waye laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ ati Aye tun waye lọjọ Ẹti to kọja yii l’Atan-Ọta, ipinlẹ Ogun. Nibi ti wọn ti n yinbọn mọra wọn lawọn ọlọpaa ti de, tọwọ fi ba awọn gende mẹrin yii: Oluṣẹgun Owoọla, Gbenga Akinkade, Jinadu Waliu ati Sanni Hammed.

Alaye ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, ṣe nipa wọn ni pe ni nnkan bii aago mẹrin idaji kutu ọjọ naa ti i ṣe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu keje yii, niṣe lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹye ati Aye tun bẹrẹ ija agba lopopona kan ti wọn n pe ni Hotel, l’Atan-Ọta. O ni ija naa gboro pupọ, niṣe ni wọn n yinbọn lakọlakọ sira wọn lai ṣiwọ rara. Aibalẹ ọkan lo jẹ kawọn eeyan ibẹ dọgbọn ta awọn ọlọpaa lolobo, ti DPO teṣan Atan-Ọta, CSP Abọlade Ọladigbolu, fi ko awọn eeyan rẹ lẹyin, ti wọn gba ibi ija naa lọ.

Pe awọn ọlọpaa de ko ba awọn ọmọ naa lẹru bi Oyẹyẹmi ṣe wi, niṣe ni wọn n yinbọn funra wọn lọ lai dawọ ija duro. Ṣugbọn nigba to ya ṣa, awọn ọlọpaa kapa igun mejeeji, wọn si ri awọn mẹrin yii mu. Eyi lawọn ohun tawọn ọlọpaa sọ pe awọn ba lọwọ wọn; ibọn ilewọ ibilẹ kan, ọta ibọn mẹta ti wọn ko ti i yin, ọbẹ meji, irin atawọn oogun abẹnugọngọ. Wọn ti ko wọn lọ sẹka to n ri si igbogunti ẹgbẹ okunkun nipinlẹ yii, gẹgẹ bi CP Edward Awolọwọ Ajogun ṣe paṣẹ.

Leave a Reply