Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọgọọrọ awọn ọdọ ilu Arimọgija ati Ijagba, nijọba ibilẹ Ọsẹ, ni wọn jade lati fẹhonu han ta ko akọlu awọn Fulani darandaran to n waye lemọlemọ lagbegbe naa.
Awọn olufẹhonu ọhun ni wọn mori le ṣẹkiteriati ijọba ibilẹ Ọsẹ, eyi to wa niluu Ifọn, pẹlu erongba ati fi ẹdun ọkan wọn han si alaga ijọba ibilẹ naa.
Ifẹhonu han ọhun fẹrẹ yọri si nnkan mi-in pẹlu bawọn ọdọ tinu n bi ọhun ṣe ti geeti ṣẹkiteriati Ọsẹ pa fun ọpọlọpọ wakati lori ẹsun ti wọn fi kan alaga pe o kọ lati yọju si wọn.
Gbogbo akitiyan awọn ẹṣọ alaabo to wa nitosi lati pẹtu si wọn ninu lo ja si pabo, ṣe lawọn ọdọ ọhun kọ jalẹ lati tẹti si arọwa ti wọn n pa fun wọn.
Ọkan ninu wọn to b’ALAROYE sọrọ ni o kere tan, eeyan bii mẹfa ni wọn ti dero ọrun ọsan gangan laarin osu mẹta pere tawọn Fulani ti bẹrẹ akọlu wọn lagbegbe Arimọgija ati Ijagba.
O ni akọlu ọhun si tun n tẹsiwaju lẹyin gbogbo igbesẹ tijọba ipinlẹ Ondo loun ti gbe lati fopin si wahala awọn Fulani agbe-sunmọmi ọhun.