Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina Rotimi Akeredolu ti rọ ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹ-ede yii lati tete gbe igbesẹ lati peṣe aabo to yẹ lawọn ọgba ẹwọn gbogbo to wa kaakiri ipinlẹ Ondo.
Arọwa yii waye ninu atẹjade kan ti gomina ọhun fi sita lati ọwọ Akọwe iroyin rẹ, Richard Ọlabọde, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.
Arakunrin ni ọrọ akọlu tawọn janduku kan ṣe sawọn ọgba ẹwọn to wa nipinlẹ Kogi, Ekiti ati eyi to ṣẹṣẹ waye niluu Ọyọ lopin ọsẹ to kọja yẹ ko jẹ ẹkọ fawọn ẹsọ alaabo.
Aketi ni oun nigbagbọ pe awọn amookunsika kan lo wa nidii gbogbo akọlu to n waye ọhun lati maa tu awọn ogbontarigi ẹlẹwọn kan silẹ pẹlu ete ati erongba to jẹ awọn nikan lo ye.
Ọpọlọpọ awọn janduku ti wọn koju ọkan-o-jọkan igbẹjọ bii ipaniyan, ijinigbe, ifipabanilopọ ati biba awọn oko oloko jẹ lo ni wọn ṣi wa lawọn ọgba ẹwọn to wa kaakiri nipinlẹ Ondo.
Bakan naa lo ni awọn afurasi apaayan tọwọ tẹ lori iku Funkẹ Ọlakunrin to jẹ ọmọ Baba Reuben Faṣọranti si wa ni ahamọ ibi tí wọn fi wọn pamọ si latari igbẹjọ wọn to si n lọ lọwọ n’ile-ẹjọ giga.
Gomina Akeredolu ni loootọ lawọn ẹsọ Amọtẹkun n gbiyanju, tí wọn si n ṣiṣẹ takuntakun lati ri i daju pe eto aabo ẹmi ati dukia fẹsẹ mulẹ nipinlẹ Ondo, sibẹ, o ni o yẹ ki ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede Naijiria ṣeto ati ko ọgọọrọ awọn ọlọpaa wa si i, ki wọn le maa mojuto awọn ọgba ẹwọn naa nitori iku to n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni.
Arakunrin tun fi asiko naa rọ awọn eeyan ipinlẹ ọhun lati maa fura, ki wọn si maa ṣakiyesi gbogbo ohun to ba n sẹlẹ lagbegbe wọn daadaa.
O rọ awọn araalu lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹsọ alaabo, ki wọn si gbiyanju lati tete maa fi awọn nnkan kayeefi tabi ajoji ti wọn ba ri ni sakaani wọn to awọn ọlọpaa leti.