Latari b’awọn sọja ṣe binu kuro loju ọna marose l’Ondo, ẹgbẹ PDP sọko ọrọ si Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ọkan-o-jọkan ọrọ kobakungbe lawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC ti n fi ṣọwọ sira wọn latari bawọn ọmọ ologun ṣe deedee kẹru wọn kuro lawọn oju ọna marosẹ gbogbo to wa kaakiri ipinlẹ Ondo.

Kayeefi lo jẹ fawọn eeyan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pẹlu bi wọn ko ṣe ri awọn ọmọ ologun ọhun gẹgẹ bii iṣe wọn lawọn oju ọna Marosẹ bii Akungba si Ikarẹ Akoko, Ọwọ si Akungba, Ondo si Akurẹ, Oke-Igbo si Ile-Ifẹ, Ọrẹ si Ondo ati Akurẹ si Ikẹrẹ-Ekiti.

Ohun tawọn eeyan kọkọ ro ni pe ọrọ eto idibo gomina to fẹẹ waye nipinlẹ Anambra lọjọ Abamẹta, Satide to n bọ yii, ni wọn tori rẹ ko wọn lọ lati lọọ peṣe aabo fawọn eeyan.

Ọrọ yii lo si n ja ran-in ran-in nilẹ lọwọ ti Akọwe iroyin ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ondo, Kennedy Ikantu Peretei, fi gbe atẹjade kan sita lojiji nirọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, eyi to pe akọle rẹ ni ‘Kikuna Akeredolu lati sanwo ajẹmọnu fawọn ẹṣọ alaabo, ajalu nla ni fawọn araalu,  …awọn sọja binu kuro loju ọna marosẹ,  ….awọn Nefi naa ti n pete ati kuro loju omi’

Ninu alaye to ṣe siwaju sinu atẹjade naa, Kennedy ni ko si ani-ani pe owo ajẹmọnu awọn ẹṣọ alaabo wọnyi ti Arakunrin kọ lati san lo bi awọn ṣọja ninu ti wọn fi kuro loju ọna marosẹ atawọn aala ipinlẹ Ondo ti wọn n sọ.

O ni fun ọpọlọpọ ọdun sẹyin ni adari awọn ọmọ ologun lorilẹ-ede yii ti fọwọ si i ki awọn sọja maa ṣọ awọn ibi to ṣe koko bii mejilelọgbọn nipinlẹ Ondo lati pinwọ iwa ijinigbe atawọn iwa ọdaran mi-in lawujọ.

O ni adehun to wa laarin awọn ọga sọja yii atawọn ijọba to ti wa ṣaaju Akeredolu ni pe wọn gbọdọ maa fun awọn ọmọ ologun naa lowo taṣẹrẹ loṣooṣu latari iṣẹ aabo ti wọn n ṣe.

Kennedy ni lati bii oṣu mẹrin sẹyin ni Aketi ti kọ ti ko sanwo naa mọ, nibi tọrọ yii le de, ọpọ awọn ọba alaye to wa nipinlẹ Ondo lo ni wọn da si i pẹlu bi wọn ṣe bẹ gomina titi, ṣugbọn to faake kọri lati sanwo to jẹ wọn.

O ni ti Aketi ko ba tilẹ fẹẹ bikita, o yẹ ko le ro ti odidi ọba, iyẹn Olufọn tilu Ifọn, ti wọn pa nipakupa nitosi ilu rẹ lọdun to kọja ati tawọn ọba bii mọkanla mi-in ti wọn ti ko sọwọ awọn ajinigbe laarin ọdun kan ṣoṣo nipinlẹ Ondo.

Agbẹnusọ ẹgbẹ PDP ọhun waa fi asiko naa rọ Gomina Akeredolu ko tẹti gbọ ẹbẹ awọn eeyan Ondo nipa ṣiṣe eto kiakia lori bi awọn sọja to binu lọ yoo ṣe tun pada ṣoju ọna, nibi ti wọn ti n ṣeto aabo fawọn araalu atawọn arinrin-ajo nitori pe ojuṣe ijọba ni lati peṣe aabo to peye fawọn eeyan to n ṣejọba le lori.

Nigba to n fun Kennedy lesi ọrọ rẹ, Kọmisanna feto iroyin nipinlẹ Ondo, Donald Ọjọgo, ni ainiṣẹ lo n yọ ẹgbẹ PDP lẹnu nitori pe tí wọn ba niṣẹ gidi lọwọ, wọn ko ni i raaye maa fi nnkan to ṣe koko bii eto aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ṣe oṣelu lasan.

O ni oun mọ pe ọrọ ẹgbẹ PDP ko ni i ta rara leti awọn eeyan nitori pe awọn ajọ ologun tọrọ kan gan-an ko sọrọ mọ, ki waa lo de ti ẹgbẹ PDP fẹẹ sọ ara wọn di agbọrandun lasan.

Ọjọgo ni ki awọn ẹgbẹ alatako ma wulẹ yọ ara wọn lẹnu lori ọrọ ti ko kan wọn nitori pe digbi lawọn ẹsọ Amọtẹkun wa nikalẹ lati koju ipenija eto aabo to ba fẹẹ yọju.

 

Leave a Reply