Latari bi wọn ṣe n digun ja awọn ileepo lole l’Akurẹ, ijọba tun fofin de ọkada gigun nipinlẹ Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ijọba ipinlẹ Ondo tun ti kede fífi ofin de iṣọwọ-ṣiṣẹ awọn ọlọkada lawọn ilu nla nla to wa kaakiri ipinlẹ naa.

Ikede yii waye lati ẹnu alakooso gbogbogboo fun ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ naa, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, lasiko to n bawọn oniroyin kan sọrọ l’Akurẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

O ni igbesẹ yii pọn dandan lati dena bawọn adigunjale kan ṣe n paayan kaakiri awọn ileepo to wa l’Akurẹ, ti wọn si tun n ja wọn lole.

Ileepo bii mẹta lo ni awọn agbewiri naa ti ṣọsẹ niluu Akurẹ nikan laarin oṣu kan pere, nibi ti wọn ti yinbọn pa awọn ẹni ẹlẹni, ti wọn si tun ko ọpọlọpọ owo lọ.

O ni awọn ti fidi rẹ mulẹ nínú iwadii awọn pe aarin aago meje si mẹsan-an alẹ lawọn janduku ọhun fi n ṣiṣẹ ibi wọn pẹlu ọkada.

Adelẹyẹ ni idi ree tijọba tun fi pinnu lati fofin de gigun ọkada laarin aago meje aṣaalẹ si aago mẹfa aarọ ọjọ keji.

Bakan naa lo ni ijọba ti ṣetan lati maa fun gbogbo awọn ọlọkada to n fi ọkada wọn gbero ni kaadi idanimọ ti yoo fun awọn ẹsọ alaabo lanfaani lati da ojulowo ọlọkada mọ yatọ si awọn to n fi ọkada gigun boju huwa ọdaran.

O ni ko si ẹbẹ tàbí awawi fun ẹnikẹni tọwọ ba tẹ pe o ru ofin tijọba ṣẹṣẹ tun fi lele naa, dandan ni kiru ẹni bẹẹ jiya to tọ labẹ ofin.

 

 

Leave a Reply