Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ẹgbẹ OPC, ẹka tipinlẹ Ondo, ti fẹhonu han lori bawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ṣe n pa awọn ọmọ ẹgbẹ wọn nipakupa niluu Ọwọ ati agbegbe rẹ.
Ninu lẹta kan ti wọn kọ si Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Bọlaji Salami, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni wọn ti fẹdun ọkan wọn han lori itu tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹiyẹ n pa niluu Ọwọ ati agbegbe rẹ.
Alaye ti wọn ṣe sinu iwe ti wọn kọ ni pe ni kete ti eto idibo gomina to waye lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2020, ti pari lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii ti tun ko ara wọn jọ, ti wọn si n doju ija kọ gbogbo awọn ti wọn ri bii alatako lasiko eto idibo naa.
Gbogbo iwa janduku tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii n hu ni wọn lo lọwọ ọkan ninu awọn amugbalẹgbẹẹ gomina to jẹ ọmọ bibi ilu ọhun ninu.
Ninu alaye ti wọn ṣe siwaju, ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ to kọja, ni wọn lawọn janduku ọhun lọọ ka ọkan ninu awọn ọmọ ẹgbẹ OPC, Ọla, mọle, ti wọn si pa a nipakupa.
Wọn ni awọn kọkọ fi iṣẹlẹ ọhun to awọn ọlọpaa ilu Ọwọ leti ki awọn too bẹrẹ igbesẹ lori bi oku ẹni ti wọn pa naa yoo ṣe di sisin lọjọ keji ti i ṣe ọjọ Iṣẹgun, Tusidee.
Ẹgbẹ OPC ni ibi tawọn ti n sinku oloogbe naa lọwọ lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yii tun ti waa kọ lu awọn, ti wọn si ran eeyan mẹfa sọrun ọsan gangan, wọn dana sun ile meji lagbegbe Idasen ati Ijẹbu Ọwọ, bẹẹ ni wọn tun jo olu ile ẹgbẹ wọn to wa nijọba ibilẹ Ọwọ.
Wọn ni ọpọlọpọ awọn oloye ẹgbẹ awọn ni wọn ti sa kuro niluu nitori pe titi di asiko yii lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa ṣi n rin kiri pẹlu ọkan-o-jọkan awọn nnkan ija oloro lọwọ wọn, ti ko si sẹni to da wọn lẹkun.
Awọn ọmọ ẹgbẹ OPC waa rọ kọmisanna ọlọpaa láti tètè wa nnkan ṣe sọrọ naa nitori pe ọga awọn ìyẹn Iba Gani Adams, lo ṣi n ka awọn lọwọ ko ti awọn ko fi ti i maa gbẹsan iku awọn eeyan awọn ti wọn pa.
Bakan naa ni wọn rọ Gomina Rotimi Akeredolu lati tete kílọ fun amugbalẹgbẹẹ rẹ to n da omi alaafia ilu Ọwọ ru ki ọrọ naa too bọwọ sori patapata.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, rogbodiyan to waye naa lo ṣokunfa bi Ọlọwọ tilu Ọwọ, Ọba Ajibade Gbadegẹsin Ogunoye, ṣe pe ipade pajawiri si aafin rẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Gbogbo awọn oloye ilu, awọn olori ẹlẹsin, awọn olori ẹgbẹ, iyalọja, olori agboole, ọdọ, awọn awakọ atawọn ọlọkada ni wọn peju pesẹ sinu ipade naa.
Ohun ti gbogbo wọn si fẹnu ko le lori lopin ipade ọhun ni pe ki gbogbo ilu fọwọsowọpọ lati fopin si bawọn ọdaju eeyan kan ṣe n ta ẹjẹ awọn alaisẹ silẹ niluu Ọwọ ati agbegbe rẹ.
Wọn pasẹ fun gbogbo awọn oloye agboole lati maa mojuto ayika wọn, ki wọn si tete maa fi ohun tí wọn ba ṣakiyesi pe o le di alaafia ilu lọwọ to awọn ẹsọ alaabo leti.