Lati Eko lawọn ọmọde wọnyi ti waa wọ miliọnu kan jade lakanti awọn ẹlẹran l’Abẹokuta

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

To ba jẹ bawọn ọmọde iwoyi ṣe mọ apade-alude ẹrọ ayelujara ni wọn fi n ọgbọn rẹ ṣe aye loore ni, ọga ni Naijiria yii ko ba jẹ ninu awọn orilẹ-ede lagbaaye.

Obinrin ni Esther Bukọla Audu to tun n pe ara ẹni Ọshin, Ọbantoko lo n gbe l’Abẹokuta, ẹni ọgbọn ọdun si ni. Ọmọbinrin naa lo ni ẹnikan fẹẹ fi ẹgbẹrun meji naira ranṣẹ soun, foonu oun toun le fi gba alaati towo naa ba wọle si ti bajẹ, nitori naa, ki ọrẹ oun, Gbemisọla Mọsaku, jẹ ki owo naa wọ inu akanti rẹ koun le mọ to ba wọle, koun si le ri i gba.

Gbemisọla ko jiyan, oun gbe foonu rẹ le Esther lọwọ, o fi  kaadi ATM rẹ naa si i pe towo ọhun ba wọle ko le baa mọ, ko si le lọọ gba a.

Awọn ẹgbọn Gbemisọla mẹta ti wọn n ṣiṣẹ apata ẹran lo ni akanti ti  Gbemi fun ọrẹ ẹ yii, owo maaluu ti wọn n ta lo n wọle sibẹ, owo ti wọn si ni ninu apo asunwọn naa le ni miliọnu kan.

Nigba ti tuu taosan ti Esther n reti wọle sinu akanti naa, o ri alaati lori foonu Gbemi to wa lọwọ ẹ. Bo ti ri alaati ẹgbẹrun meji naa lo ri i pe apapọ owo to wa ninu asunwọn yii jẹ miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira (1.5m), nigba naa ni ara ọmọbinrin to kawe de ipele ND ni Poli ipinlẹ Ọṣun naa bu maṣọ, n lo ba pe ọrẹ ẹ to n jẹ Busayọ Adeoti pe ṣe o mọ ọna teeyan le fi wọke, iyẹn wọ owo olowo jade lakanti lai jẹ pe ẹni to ni owo mọ.

Busayọ, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, to n gbe ni Kọla, nipinlẹ Eko, loun ko mọ iru ọgbọn bẹẹ, n loun naa ba fi lọ Titilayọ Morakinyọ, ọmọ ileewe Gateway ICT  Poli to wa ni Ṣaapade, pe abi iyẹn mọ ọna tawọn le gbe e gba towo olowo naa yoo fi jade.

Titilayọ naa ko mọ ọna yii, ṣugbọn aburọ rẹ ọkunrin to n jẹ Mayọwa Morakinyọ, ọmọ ọdun mọkandinlogun, mọ kisa ninu iṣẹ ‘Yahoo’, oun lo bẹrẹ si i ba Esther sọrọ lati Eko, ti Esther ọlọmọ meji si bẹrẹ si i fun un ni nọmba igbowo lori kaadi ATM ti Gbemisọla fun un, bẹẹ lo tun fun wọn ni nọmba mẹrin to gbẹyin lara kaadi naa. Bi Mayọwa  ṣe bẹrẹ iṣẹ jibiti yii ree, o si ri i ṣe.

Kinni kan ti ọmọkunrin naa kan sọ fun Esther ni pe oun ko le gba owo naa ni banki, ki wọn ma baa mu oun. O ni ọgbọn kan to wa ni pe koun fi awọn owo toun fẹẹ wọ jade naa ra oja lori ẹrọ ayelujara, iyẹn lawọn ileetaja igbalode bii Jumia.

Esther to bẹ ẹ lọwẹ naa sọ pe iyẹn naa daa, ṣebi bawọn ba ra ọja jade tan, awọn le tun un ta kawọn si ri owo awọn. Bo ṣe di pe wọn ra foonu Iphone lati ọdọ Jumia niyẹn, wọn si ra oriṣii foonu olowo nla mẹta mi-in, gbogbo eyi waye ninu oṣu kẹjọ, ọdun yii.

Awọn mẹta kan ni wọn ra foonu naa labule Kọmputa (Computer Village), n’Ikẹja.  Awọn ọlọpaa sọ pe Adewumi Ọlanrewaju lo ra foonu naa lọwọ Mayọwa, wọn ni foonu ti wọn n ta lẹgbẹrun lọna irinwo le lọgọrin (380,000) niṣe lo ra a lọwọ ọmọ naa lẹgbẹrun lọna igba ati ogoji naira (240,000).

Gbogbo foonu naa ni Mayọwa ta, o fi owo to din diẹ lẹgbẹrun lọna irinwo (367,000) ranṣẹ si Esther to gbe iṣẹ wa, o ra foonu ẹlẹgbẹrun mẹrinlelọgbọn fun ẹgbọn ẹ, Titilayọ ti wọn jọ jẹ ọmọ iya ati baba kan naa. Esther paṣẹ fun Mayọwa pe ko fi ẹgbẹrun mọkandinlaaadọta (49,000) ranṣẹ si Busayọ Adeoti, iyẹn naa gba a lai gbe, lai fa, bẹẹ ni Mayọwa to wọ owo jade naa gba ẹgbẹrun lọna igba naira (200,000)

Nigba ti Gbemisọla yoo fi mọ pe nnkan ti n ṣẹlẹ ninu akanti to n ba awọn ẹgbọn ẹ ti ko mọwe mojuto, nnkan ti bajẹ. Ọjọ kẹjọ, ninu oṣu kẹsan-an to kọja yii, lo ṣẹṣẹ lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Adatan, l’Abẹokuta, lawọn ọlọpaa ba bẹrẹ igbesẹ ati mu awọn to ṣiṣẹ naa.

Wọn wa Adewumi Ọlanrewaju to ra foonu naa de Ikẹja, niṣe loun pe awọn ọmọọta le awọn ọlọpaa to fẹẹ mu un lori, ni wọn ba lu ọlọpaa naa, bẹẹ ni wọn n pariwo pe ijọba ti fofin de SARS, kawọn ọlọpaa naa lọọ jokoo sibi kan.

Ṣugbọn awọn ọlọpaa naa pada ṣiṣẹ wọn, ọwọ si tun tẹ Ṣanni Habib ati Tọmiwa Adeọṣun tawọn naa mọ nipa ọja ole ti Adewumi ra.

Gbogbo wọn pata ni wọn foju wọn han ni Eleweeran l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹwaa yii, wọn si jẹwọ pe loootọ ni Esther gbe iṣẹ wa, gbogbo awọn si jọ pin owo iṣẹ naa ni.

Ṣugbọn bi wọn ṣe gba owo naa to, ko sẹni kan ninu wọn to le tọka si ohun kan bayii to fi ṣe, anadanu ni wọn nawo naa. Esther to mu iṣẹ wa ko ri nnkan ẹyọ kan bayii sọ pe oun fi owo naa ṣe. Busayọ ni tiẹ sọ pe ajẹẹlẹ gbese ounjẹ bii irẹsi toun ti gba lọwọ awọn eeyan laduugbo loun fowo oun san.

O loun ko lọkọ, oun lọmọ meji lọwọ, oun ṣaa fowo naa jẹun, oun si fi tọju iba to n ṣe oun.

Mayọwa to wọ owo olowo jade sọ pe oun naa ṣe faaji, oun ra foonu fẹgbọn oun, oun ra funra oun naa, n lowo ba tan.

Ṣa, awọn ọlọpaa sọ pe wọn ti n da owo naa pada ni gbogbo ọna. Wọn ni ṣugbọn iyẹn ko ni ki wọn ma de kootu o, wọn ni laipẹ lai jinna, ni awọn ọmọde meje ọlọgbọn alumọkọrọyi naa yoo foju bale-ẹjọ lori jibiti, awọn ti wọn lu ọlọpaa ninu wọn naa yoo si jẹjọ iyẹn lọtọ ni.

One thought on “Lati Eko lawọn ọmọde wọnyi ti waa wọ miliọnu kan jade lakanti awọn ẹlẹran l’Abẹokuta

Leave a Reply