Lati Eko ni Ṣẹgun atọrẹ ẹ ti lọọ ji ewurẹ gbe n’Ibadan tọwọ Amọtẹkun fi tẹ wọn

Jọkẹ Amọri

Lati adugbo Alapẹrẹ to wa ni Ketu, niluu Eko, ni awọn ọrẹ meji kan, Ṣẹgun Ọladipọ, ẹni ogoji ọdun, ati Wale Samuel, toun naa jẹ ẹni ogoji ọdun, ti gbera, ti wọn lọ si awọn adugbo kaakiri ipinlẹ Ọyọ ati Ọṣun, ti wọn si ji ọpọlọpọ ewurẹ kọwọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọyọ too tẹ wọn.

Awọn afurasi yii ti ji ewurẹ bii mejidinlogun ni agbegbe Old Ifẹ Road, nijọba ibilẹ Ẹgbẹda, niluu Ibadan, ki ọwọ ẹṣọ Amọtẹkun too tẹ wọn pẹlu awọn ẹru ofin naa.

Ẹran ewurẹ mejidinlogun ti wọn jẹ aaye, ọkọ Masida ti nọmba rẹ jẹ EPE 857 HM, ẹgbẹrun mejilelaaadọta Naira le diẹ ati awọn nnkan mi-in ni wọn ba lọwọ wọn.

Awọn eeyan naa jẹwọ pe awọn ti lọọ ji ewurẹ ni awọn agbegbe kan ni kan ni ilu Oṣogbo ati Ọdẹ-Omu, ki awọn too waa tun ṣe iru iṣẹ kan naa yii niluu Ibadan.

Oju-ẹsẹ ni awọn agbofinro ibilẹ yii ti mu wọn, ti ọkan ninu awọn ọga wọn to n ri si awọn iṣẹ akanṣẹ, Ọgbẹni Oluṣọla Ọladunjoye, si fidi rẹ mulẹ pe awọn ti fa wọn le awọn agbofinro lọwọ fun ijiya to tọ.

Leave a Reply