Lati Eko ni Morufu atawọn ẹgbẹ ẹ ti lọọ digunjale l’Ogun tọwọ fi te wọn

Gbenga Amos,  Abẹokuta

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ marun-un ninu awọn adigunjale kan to maa n ti ipinlẹ Eko lọọ ja awọn eeyan lole lawọn ilu bii Ipẹru, Sagamu ati Ode Rẹmọ, nipinlẹ Ogun. Awọn tọwọ ba ninu wọn ni: Moruf Abidogun, Usman Adeyẹmi, Fsayọ Aliu, Afees Adeṣina ati Dauda Lekan.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

O ṣalaye pe ipinlẹ Eko ni awọn eeyan naa n gbe, ṣugbọn wọn maa n wa si awọn ilu kaakiri ipinlẹ Ogun lati ṣiṣẹ ibi wọn. Agbegbe Ogere, ni wọn ti maa n da awọn eeyan lọna, ti wọn si maa n gba dukia ti wọn ba ba lọwọ wọn.

Lasiko ti wọn n ṣiṣẹ buruku yii lọwọ tẹ wọn. Gẹgẹ bi Oyeyẹmi ṣe sọ, awọn araadugbo lo pe DPO Ipẹru pe awọn eeyan naa n ṣọṣẹ ni adugbo naa. Eyi lo mu ki SP waheed Oni ko awọn ikọ rẹ sodi, ti wọn si lọ si agbegbe ti wọn ti n da awọn eeyan lọna yii.

Ṣugbọn bi wọn ti ri awọn agbofinro ni wọn fere si i, ti wọn si fi mọto Toyota ti nọmba ẹ jẹ GGE733 FL, ti wọn ṣẹṣẹ ja gba lọwọ ẹnikan silẹ. Bi wọn ṣe n sa lọ lawọn ọlọpaa gba ya wọn, wọn si ri marun-un mu ninu wọn.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe ki wọn taari wọn si ẹka to n gbọ ẹsun iwa ọdaran. Lẹyin iwadii ni wọn yoo gbe awọn adigunjale naa lọ sile-ẹjọ gẹgẹ bi Oyeyẹmi ṣe sọ.

Leave a Reply