Lati ipinlẹ Eko lawọn mẹta yii ti waa jale l’Ogun

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

 

Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ awọn ọdọkunrin mẹta kan, Samuel Sunday; ẹni ogun ọdun, Mustapha Adelẹke; ẹni ọdun mejilelogun ati Joel Rotimi, ẹni ọdun mọkandinlogun.

Ole ni wọn mu wọn pe wọn n ja l’Ajuwọn, nipinlẹ Ogun. Bẹẹ, Eko ni Samuel ati Mustapha ti wa, Joel nikan lo n gbe l’Agbado, nipinlẹ Ogun.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, sọ pe Fagba ni Samuel n gbe, Mustapha n gbe ni Ajala, awọn mejeeji sowọ pọ pẹlu Joel to n gbe lagbegbe Taju Bello, l’Agbado, wọn si lọ si Ajuwọn lọjọ kẹrinla, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, wọn bẹrẹ si i ja awọn eeyan ibẹ lole ni nnkan bii aago meji ku iṣẹju mẹẹẹdogun loru.

Awọn ẹlẹgiri naa to mẹfa gẹgẹ bi Alukoro ṣe wi, ṣugbọn awọn mẹta yii lọwọ tẹ nigba tawọn ọlọpaa gba ipe to ta wọn lolobo pe awọn eeyan agbegbe Iju aga, l’Ajuwọn, wa ninu ewu.

DSP Andrew Akinṣẹyẹ ti teṣan Ajuwọn ko awọn eeyan rẹ lọ sibẹ, awọn ọmọ to n daamu adugbo naa si sa lọ bi wọn ṣe ri awọn ọlọpaa, ṣugbọn ọwọ ba awọn mẹta yii ni tiwọn.

Ibọn ilewọ ibilẹ kan, ọkada Bajaj mẹrin, igbo mimu, kaadi idibo meji ati kaadi idanimọ orilẹ-ede Naijiria meji ni wọn gba lọwọ awọn tọwọ ba yii.

Bi wọn ṣe ko wọn lọ sẹka iwadii gẹgẹ bii aṣẹ CP Edward Ajogun naa ni awọn ọlọpaa fi nọmba tawọn eeyan le pe bi wọn ba kofiri ole laduugbo wọn sita. Awọn nọmba naa ni: 08081770416 ati 08081770419

Leave a Reply