Lati Lalupọn ni Sikiru ati Ọlayẹmi ti lọọ jale l’Ọta tọwọ fi ba wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Iṣẹ aje ni wọn lo n sọmọ nu bii oko, ole jija lo gbe awọn gende meji yii, Ọlanrewaju Sikiru ati Ọlayẹmi Obiṣẹsan, de Ọta, nipinlẹ Ogun, ni tiwọn. Bẹẹ, Lalupọn, nipinlẹ Ọyọ, ni wọn ti wa, kọwọ palaba wọn too segi lọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, nibi ti wọn ti n fi tiwọn pa odidi ẹsteeti lẹkun.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun, lo fiṣẹlẹ yii to ALAROYE leti. O ṣalaye pe ni nnkan bii aago kan aabọ ooru ọjọ Sannde naa ni awọn kan pe DPO teṣan Àgbárá, nipinlẹ Ogun, pe awọn adigunjale ti ya bo ibi kan ti wọn n pe ni Area 8, OPIC Estate, nijọba ibilẹ Ado-Odo/Ọta, wọn si ti bẹrẹ si i pa awọn eeyan ibẹ lẹkun pẹlu nnkan ija ti wọn gbe dani gbogbo.

Awọn ọlọpaa lọ sibẹ gẹgẹ bi Alukoro wọn ṣe wi, wọn si ba ikọ adigunjale kan nibẹ ti wọn n ṣorọ lọwọ.

Niṣe ni wọn tiẹ dabọn bolẹ fawọn ọlọpaa gẹgẹ bii alaye Oyeyẹmi, ṣugbọn nigba tawọn agbofinro naa jẹ ki wọn mọ pe awọn ko ba tere wa ni awọn kan sa lọ ninu awọn ẹlẹgiri naa, koda, ibọn ti ba wọn ki wọn too sa lọ.

Awọn meji yii lọwọ ọlọpaa tẹ, Ọlanrewaju Sikiru, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28) ati Ọlayẹmi Obiṣẹsan; ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn(25).

Awọn mejeeji jẹwọ pe awọn ki i ṣe ara Ọta, wọn ni Lalupọn, lagbegbe Ibadan, nipinlẹ Ọyọ, lawọn ti waa jale l’Agbara, wọn lawọn waa darapọ mọ awọn yooku awọn to wa l’Agbara ni.

Ibọn ilewọ ibilẹ meji to jẹ ẹlẹnu meji lawọn ọlọpaa ba lọwọ wọn, ọta ibọn mejila ti wọn ko ti i yin wa nibẹ, bẹẹ ni meji mi-in ti wọn ti yin wa nibẹ pẹlu. Wọn ba kọmputa agbeletan meji ti i ṣe HP lọwọ wọn, foonu mejidinlogun, ẹgbẹrun mẹrinla aabọ naira ati ṣenji diẹ(14,590) pẹlu ọkada Bajaj kan.

Wọn ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ ninu iwadii wọn, bẹẹ ni awọn agbofinro ṣi n wa awọn yooku wọn to gbe ọta ibọn sa lọ.

Leave a Reply