Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, ni Gomina ipinlẹ Kwara, Abdulrahman Abdulrasaq, ṣe ifilọlẹ aṣọ iṣẹ tuntun fawọn ọlọkada lati le mu ki eto aabo gbopọn si i.
Ṣaaju nijọba ti gbe awọn igbimọ kan kalẹ lati wa ọna abayọ si bi wọn yoo ṣe tete maa da awọn ọlọkada to n ṣiṣẹ nigboro mọ, eyi ti Kọmiṣanna to n ri si ọrọ iṣẹ nipinlẹ Kwara, Rotimi Iliasu, jẹ alaga wọn.
Igbesẹ yii ni wọn ni yoo mu ayipada ba eto aabo ti ko rajaja nipinlẹ naa, tawọn araalu yoo maa sun oorun asun fori le oṣuka, tijọba yoo si fọwọsowọpọ pẹlu ẹgbẹ ọlọkada (ORAN), ẹka tipinlẹ Kwara, ki erongba ijọba le wa simuṣẹ.
Nigba ti gomina n sọrọ nibi ifilọlẹ naa lo ti sọ pe idi kan pataki ti iṣejọba oun fi ṣagbekalẹ aṣọ iṣẹ tuntun fun awọn ọlọkada ni pe ki awọn araalu le maa da ojulowo ọlọkada mọ, ki eto aabo si le daa si i nipinlẹ Kwara, tori pe oniruuru iroyin ijinigbe lo ti gba igboro, to si jẹ ọkada ni ọpọ awọn ajinigbe ọhun maa n lo lati fi ṣiṣẹ aburu naa.
O ni igbesẹ yii yoo mu ka daabo bo ara wa nigba ta a ba ti da awọn ọlọkada naa mọ.
O tẹsiwaju pe eyikeyii ọlọkada ti ọwọ ba tẹ to lọwọ ninu lilẹdi apo pọ mọ awọn ajinigbe, ijọba yoo fi iru wọn jofin.
Gomina waa rọ gbogbo araalu pe ti wọn ba ti fẹẹ gun ọkada ti omi inu n kọ wọn bọya ajinigbe ni tabi ki i ṣe ajinigbe, wọn le ya foto nọmba ọlọkada to ba gbe wọn, ki wọn si fi ṣọwọ si eeyan wọn, eyi ni yoo jẹ ki wọn le wa nọmba ọlọkada naa lawaari.