Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Anfaani ṣi wa fawọn ti ko ba ti i gba abẹrẹ ajẹsara Korona nipinlẹ Ogun lati tete ṣe bẹẹ, nitori to ba fi le di ọjọ kin-in-ni, oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ, awọn ti ko ba ti i gba a ko ni i le wọ ọkọ ero, wọn ko ni i jẹ ki ọkada gbe wọn mọ, wọn ko ni i wọle iṣẹ ijọba pẹlu, bẹẹ ni wọn ko ni i gba wọn laaye lọja ati nileewe ijọba.
Gomina Dapọ Abiọdun lo sọ eyi di mimọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii,ti i ṣe ọjo kin-in-ni, oṣu kọkanla, ọdun 2021. Oke-Mosan, l’Abẹokuta, ni gomina ti sọrọ yii lasiko to n ṣefilọlẹ ipolongo gbigba abẹrẹ ajẹsara to n dena arun Korona.
Abiọdun sọ pe afojusun ijọba ni lati fun eeyan miliọnu meji labẹrẹ yii nipinlẹ Ogun, lati dena itankalẹ arun aṣekupani naa.
O ni awọn ti ṣafikun ibudo ti wọn ti n gba abẹrẹ yii, dipo ọgọrun-un kan ati mọkanlelọgbọn (131) to wa tẹlẹ, o lo ti di ẹẹdẹgbẹta ati mẹsan-an bayii ( 509), o si wa fawọn eeyan tọjọ ori wọn bẹre lati ọdun mejidinlogun soke.
Bi wọn ba ti n gba abẹrẹ naa ni wọn yoo maa fun wọn ni kaadi to jẹ ẹri pe wọn ti gba a, kaadi naa ni ami idanimọ ti wọn yoo maa mu kiri lati ṣafihan pe awọn ti gba a. Ẹni ti ko ba waa ni kaadi yii, a jẹ pe ko ti i gba abẹrẹ ọhun niyẹn, ijọba ko si ni i ba a ṣe.
Aaye wa lati gba a lati ọjọ kin-in-in, oṣu kọkanla yii, titi di ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kejila, ọdun 20201, lẹyin gbedeke ọgọta ọjọ yii, gomina sọ pe o pari niyẹn.