Lati Sagamu ni Afeez ti lọọ yọ eyin oku to fẹẹ fi ṣoogun owo ni itẹkuu kan n’Ileṣa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Lasiko ti ọmọkunrin ẹni ọdun mẹtalelọgbọn kan, Afeez Odusanya, n yọ eyin oku to fẹẹ fi ṣoogun owo lọwọ ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọṣun tẹ ẹ.
Afeez, mẹkaniiki ọkọ akoyọyọ (Truck), ni wọn ka eyin mejila pẹlu eegun-ika ọwọ meji mọ lọwọ.
Alakooso Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Amitolu Shittu, ṣalaye pe nigba ti wọn mu Afeez, babalawo to maa n ṣoogun owo fawọn eeyan lo pe ara rẹ.
Shittu sọ siwaju pe ilu Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, ni Afeez n gbe, latibẹ lo si ti lọ si itẹ-oku kan niluu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun, nibi to ti hu oku to yọ eyin rẹ ọhun.
Nigba to n sọrọ, Afeez sọ pe ọdun 2016 loun hu oku akọkọ, ti oun fẹẹ fi ṣoogun owo, ṣugbọn gbogbo igbiyanju oun latigba naa ni ko so eeso rere.
O ni tẹlẹtẹlẹ, ọgbọn iṣẹju loun maa n lo lati yọ eyin kan ṣoṣo, ṣugbọn ko to bẹẹ mọ nigba to di pe oun ti mọ ọn ṣe daadaa.

Leave a Reply