Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lati ọdun to n bọ ti awọn akẹkọọ yoo bẹrẹ taamu tuntun, ijọba ipinlẹ Ogun ti kede pe aṣọ kampala to gbajumọ daadaa, ti wọn mọ ipinlẹ naa mọ laọn akẹkọọ kaakiri ipinlẹ ọhun yoo maa lo gẹgẹ bii asọ ileewe bayii.
Ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni Gomina Dapọ Abiọdun sọrọ ọhun di mimọ lasiko to n si ile aṣọ n ṣ kọ ti wọn pe ni ‘‘Ogun Adirẹ Digital Market Place’’ to wa ni ‘June 12’ Cultural Centre, Kutọ, l’Abẹokuta.
Abiọdun ni, ‘‘Eto ti n lọ ṣẹpẹṣẹpẹ lati ri i pe lati ibẹrẹ taamu to n bọ lọ, aṣọ adirẹ yoo wa ninu ohun ti awọn akẹkọọ yoo maa lo gẹgẹ bii aṣọ ileewe lati ileewe alakọọbẹrẹ ati girama.
Mo maa ro ọpọ awọn eeayan lagbara si i, bẹẹ nijọba mi yoo ṣe igbelarugẹ ọrọ aje adirẹ si i.
Bakan naa lo rọ ijọba lati ṣe igbelarugẹ aṣọ ile wa yii pẹlu lilo o gẹgẹ bii aṣọ ilẹ wa fun eto ati ayẹyẹ yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe.