Latipinlẹ Eko lawọn ti ẹgbẹ APC fẹẹ lo lati dibo l’Ọṣun ti n bọ o – PDP

Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), nipinlẹ Ọṣun ti sọ pe aṣiri ọkan lara awọn ọna ti ẹgbẹ oṣelu APC fẹẹ lo lati ṣe magomago ibo gomina loṣu to n bọ ti tu si awọn lọwọ bayii.
PDP ṣalaye pe lati ipinlẹ Eko ni wọn ti fẹẹ ko awọn ti wọn yoo dibo nipinlẹ Ọṣun wa, wọn si ti gbe iṣẹ le ọkan lara awọn oludamọran agba fun Gomina Oyetọla lọwọ lati gba otẹẹli fun awọn ajeji yii.
Bakan naa ni wọn fesun kan egbe APC pe wọn ti pari gbogbo erongba wọn lati da wahala silẹ lawọn ijọba ibilẹ ti wọn mọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti rẹsẹ walẹ daadaa.

Adele alaga ẹgbẹ PDP nipinlẹ Ọṣun, Dokita Akindele Akintunde, tẹ pẹpẹ ọrọ yii nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Oṣogbo. O ke si Aarẹ Muhammadu Buhari ati awọn oṣiṣẹ alaabo lati tete da si ọrọ naa, ki wọn si kilọ fun ẹgbẹ oṣelu APC ko too di pe ọrọ yoo yiwọ.
Akintunde sọ siwaju pe ipinlẹ Eko ni awọn eekan ẹgbẹ APC ti ṣepade nipa awọn iwa laabi ti wọn fẹẹ hu ọhun nibẹrẹ ọsẹ yii, nibẹ ni wọn si ti lẹdi apo pọ mọ awọn alaga ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Eko lati ko awọn ọmọ ẹgbẹ wọn wa dibo l’Ọṣun.
O ni wọn ti gba aimọye ọkọ bọọsi ti yoo ko awọn tọọgi wa lati maa ji awọn apoti ibo lasiko idibo ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje ọdun yii.
O ni “Ẹgbẹ APC tun ti pinnu lati da aṣọ ajọ Amọtẹkun sọrun awọn janduku kan ti wọn yoo duro ti apoti ibo, ti wọn a si ji i gbe to ba ti to asiko kan lati le ko awọn iwe ibo ti wọn ti tẹka si funra wọn sinu ẹ.
“Bakan naa ni wọn ti ko awọn tọọgi kan de lati Niger Delta pẹlu aṣọ ayederu ṣọja lati maa halẹ, ki wọn si maa dunkooko mọ awọn oludibo lasiko idibo naa.
“A wa n ke si awọn oṣiṣẹ alaabo lati gba awọn ọrọ wa yii yẹwo, ki wọn si tete ṣe ohun to tọ lori ẹ.”
Nigba to n sọrọ lori awọn ẹsun yii, agbẹnusọ fun alaga ẹgbe APC l’Ọṣun, Kọla Ọlabisi, pe ẹgbẹ PDP nija lati mori le kootu ti gbogbo ẹsun yii ba da wọn loju.
Ọlabisi ṣapejuwe awọn ẹsun naa gẹgẹ bii ahesọ lasan ti ko lẹsẹ nilẹ, o ni ṣe ni ẹru ijakulẹ to n mi dẹdẹ n ba ẹgbẹ PDP.

Leave a Reply