Lawrence gun iyawo ẹ pa, o ni ko pọnmi sile

Faith Adebola

Baale ile kan, Lawrence Itakpe, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta yoo rojọ, ẹnu rẹ yoo fẹrẹ bo pẹlu bo ṣe gun oyawo rẹ, Rebecca, ẹni ọdun mẹtadinlaaadọta pa lori omi lasan lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Kejila, ọdun yii, ni ile wọn to wa ni Seaside Estate, Badore, Ajah, niluu Eko.

Ṣe ibinu ko mọ pe olowo oun ko lẹsẹ nilẹ, ẹyi lo ṣẹlẹ si baale ile yii nigba to tibi iṣẹ de ti ko si omi kankan ninu ile wọn to le lo. Ibinu pe ko ri omi lo nigba to tibi iṣẹ de naa lo gbe ko iyawo rẹ loju ti awọn mejeeji fi bẹrẹ ariyanjiyan.

A gbọ pe ariyanjiyan naa le debii pe niṣe ni baale ile yii lọ si ile idana, to si mu ọbẹ, lo ba da a de iyawo rẹ nibi orun, o si gun un. Oju-ẹsẹ ni obinrin yii ṣubu lulẹ, to si gbabẹ ku.

Ariwo ti iyaale ile na pa ko too ku la gbọ pe o ta si awọn araadugbo leti ti wọn fi lọ sinu ile naa. Awọn ni wọn si apda lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa Langbasa leti.

Oju-ẹsẹ ni DPO Langbasa, Stephen Abọlarin, ko awọn ọmọọṣẹ rẹ sodi, ti wọn si lọ sibi iṣẹlẹ naa, nibi ti wọn ti mu ọkọ obinrin yii ati ọbẹ to fi ṣeku pa iyawo rẹ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlopaa, Benjamin Hundeyin, ni loootọ ni Lawrence gun iyawo rẹ pa. O ni wọn ti gbe oku obinrin naa lọ si mọṣuari ijọba ni Yaba. Bẹẹ ni wọn ti mu ọkọ rẹ lọ si ileeṣẹ ọtelẹmuyẹ to n wadii ẹsun ọdaran to wa ni panti.

A gbọ pe lẹyin ti wọn ba pari iwadii ni wọn yoo gbe ọkunrin naa lọ sile-ẹjọ

Leave a Reply