Lawrence to fọmọ ẹ loyun gbadajọ ẹwọn gbere, lo ba bu sẹkun ni kootu

Faith Adebọla, Eko

Igbe o daa lẹnu agbalagba, ṣugbọn ọdaran ẹni ọdun mẹjilelogun ti wọn porukọ ẹ ni Lawrence Ekpo yii ko ribi yẹ ẹ si, ko si le mu un mọra rara, niṣe lo bu sẹkun gbaragada ni kootu l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, nigba tile-ẹjọ sọ ọ sẹwọn, ti wọn tilẹkun mọ ọn, ti wọn si kọkọrọ ẹ sagbami okun, ẹwọn gbere ni wọn da fun un, wọn lo jẹbi ẹsun fifipa ba ọmọ bibi inu ẹ laṣepọ, to si fun ọmọọdun mẹẹdogun naa loyun.

Adajọ Abiọla Ṣọladoye ti ile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun ifipabanilopọ ati iwa ọdaran abẹle (Ikẹja Domestic Violence and Sexual Offences Court), eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko, lo gbe idajọ naa kalẹ lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu ki-in-ni yii, o ni ẹri rẹpẹtẹ ti olupẹjọ ko siwaju kootu ọhun kọja iyemeji, o fidi ẹ mulẹ daadaa pe loootọ ni Lawrence jẹbi awọn ẹsun ti wọn fi kan an.

Agbẹjọro olupẹjọ, Abilekọ Bọla Akinṣẹtẹ ṣalaye pe lati oṣu kejila ọdun 2018 si oṣu kẹfa ọdun 2019 ni ọdaran naa fi n huwa ainitiju ọhun, ninu ile toun ati ọmọ bibi inu ẹ ọhun n gbe, l’Agege, l’Ekoo lo ti n fipa ba ọmọ ọhun laṣepọ, o si tẹramọ kinni ọhun titi tọmọbinrin naa fi ri oyun he. Ẹni ọdun mọkandinlogoji ni Lawrence lasiko naa.

Nigba ti awo ọrọ naa ya, ti wọn mu olujẹjọ yii, ti wọn si wọ ọ dele-ẹjọ, ẹlẹrii mẹrin ọtọọtọ tọrọ naa ṣoju wọn ni wọn jẹrii tako o, lara wọn ni ọmọbinrin naa funra ẹ, dokita to ṣayẹwo fun un, alabagbele wọn kan ati ọlọpaa to ṣiṣẹ iwadii lori ẹsun ọhun.

Ṣugbọn Lawrence ko ri ẹlẹrii kan mu jade lati fihan pe ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.

Ninu alaye tọmọbinrin naa ṣe niwaju adajọ, o ni baba oun ti kọ iya oun silẹ, o si ti fẹyawo mi-in, ṣugbọn iyawo yii ki i gbele, ọpọ igba lo maa n tirafu, bo ba si ti lọ pẹnrẹn ni baba oun yoo ti ki oun mọlẹ, ti yoo si dana ibasun ya oun, bẹẹ lo maa n halẹ mọ oun pe iku loun fi n ṣere toun ba fi le tu aṣiri naa fẹnikan.

Ọmọbinrin naa ni igba tagbara oun ko gbe e mọ loun dọgbọn sọ fobinrin kan nileewe oun, ibẹ lakara ti tu sepo, ti wọn fi fọlọpaa gbe ọdaran baba naa.

Bakan naa ni Dokita Maria Fadaka ti ọsibitu Mirabel Centre jẹrii pe ninu ayẹwo iṣegun toun ṣe fọmọbinrin naa, o han pe ẹnikan ti fipa ba a laṣepọ, ẹni naa ti dọgbẹ si i labẹ, ati pe ọmọ naa loyun airotẹlẹ.

Sibẹ pẹlu gbogbo ẹri yii, olujẹjọ naa loun o mọ nnkan kan nipa iṣẹlẹ ọhun, o ni ibiiṣẹ loun maa n wa lọpọ igba, oun o si ṣi aṣọ ọmọ oun wo ri debi toun maa ba a laṣepọ.

Lasiko idajọ rẹ, Adajọ Abiọla Sọladoye sọ pe ọrọ katikati ti ko jọra ni olujẹjọ naa n sọ, eyi si fihan pe ko sootọ ninu ọrọ rẹ, ati pe niṣe lo fẹẹ mọ-ọn-mọ ṣi ile-ẹjọ lọna, lati doju ẹjọ ru.

“Ẹgbin ọniyọrọ gbaa, to buru jai, ti ko tiẹ ṣee gbọ seti rara ni keeyan ki ọmọ bibi inu ara ẹ mọlẹ, ko maa ba a laṣepọ, iwa ainitiju ti ko ba laakaye mu rara ni. Ki i ṣe iwa ọmọluabi, ibalopọ laarin ibatan si lodi sofin.

“Nibo ni olujẹjọ yii sọ ọwọ ati iyi ara-ẹni junu si? Iru iwa ma-jẹ-a-gbọ wo ree! Iwa to hu yii fihan pe ironu rẹ ti dori kodo, ko si si laakaye kan fun un mọ, o si tun fi iwa oponu rẹ ṣakoba fun wundia ọmọ rẹ, o tun gba iyi ọmọbinrin naa sọnu.

“Mo gbadura pe k’Ọlọrun fun ọmọbinrin yii lalaafia ọkan, tori titi aye ni iru nnkan bayii yoo maa da ironu ọmọ naa ati ẹri ọkan rẹ laamu.

“Baba to yẹ ko jẹ oun lo maa daabo bo ọmọ rẹ, to yẹ ko maa gbeja rẹ lọwọ akọlu, lo waa n ṣe ọmọ naa baṣubaṣu debi to fi fun un loyun. Idajọ mi ni pe ki olujẹjọ yii lọọ lo iyoku aye ẹ lọgba ẹwọn pẹlu iṣẹ aṣekara gidi.”

Bẹẹ ni adajọ naa kede.

Leave a Reply