Layaajọ ayẹyẹ ọdun Ominira, Akeredolu dariji ẹlẹwọn mẹrinlelogoji

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lasiko to n sami ayẹyẹ ayajọ Ominira tọdun yii, ẹlẹwọn bii mẹrinlelogoji ni wọn ti ri idariji gba lati ọdọ Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu.

Ni ibamu pẹlu atẹjade ti Akọwe iroyin rẹ, Richard Ọlabọde, fi ṣọwọ sawọn oniroyin lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, o ni awọn ẹlẹwọn mejidinlogun ni wọn gba idande patapata, nigba ti Arakunrin tun yi idajọ awọn mẹrindinlọgbọn mi-in ti wọn ti dajọ iku fun pada si ẹwọn gbere.

O ni Akeredolu siju aanu wo awọn ẹlẹwọn ọhun latari ayipada rere ti wọn ri ninu aye wọn laarin asiko ti wọn fi wa ninu ọgba ẹwọn ti wọn fi wọn si.

Igbesẹ yii lo ni o wa ni ibamu pẹlu ila kin-in-ni, abala igba le mejila (212), ninu iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999.

Lẹyin eyi lo rọ awọn ẹlẹwọn naa lati takete si iwa ọdaran, ki wọn si maa yago fun ohunkohun to le mu wọn ṣi anfaani ti ijọba fun wọn lo.

Leave a Reply