Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu keji, ti i ṣe ayajọ ololufẹ, eeyan mẹrin lo jona ku loju ọna marosẹ Ijẹbu-Ode si Benin, nigba ti bọọsi akero kan gbina lagbegbe Atoyo.
Alukoro TRACE, Babatunde Akinbiyi, ṣalaye pe aago mejila ku iṣẹju mẹwaa niṣẹle yii waye. O ni bireeki ọkọ akero naa ni ko mu mọ lojiji, bẹẹ aigbọran ẹ lo tun ṣokunfa beeyan mẹrin ṣe jona kọja idanimọ ninu eeyan mẹwaa to wa ninu mọto naa.
Alukoro sọ pe tanka kan to gbe epo n lọ si Benin loju ọna marosẹ naa, o ni tanka naa n jo, eyi to jẹ ki epo inu ẹ maa da silẹ.
Awọn awakọ mi-in to ri eyi pe dẹrẹba tanka naa si akiyesi, o si duro lati wo o.
Nigba tawọn TRACE ati FRSC de ibi ti tanka epo naa duro si pẹlu bo ṣe n jo, wọn ko jẹ kawọn ọkọ mi-in to n bọ gba ọna yii mọ, wọn dari wọn kọ ibomi-in lati gba, ki wọn maa baa fara kaaṣa epo to n danu to si ṣee ṣe ko fa ijamba.
O ni ṣugbọn awakọ bọọsi yii ko tẹle imọran awọn ẹṣọ oju popo, niṣe loun kori bọ ọna ibi ti epo ti danu si rẹpetẹ naa, o si n gba ibẹ lọ.
Nibi to ti n tọ ọna ọhun lọ ni ijanu ọkọ rẹ ko ti mu mọ lojiji, lo ba kori bọ inu igbo to wa nitosi, o si lọọ kọ lu igi kan to duro, nibẹ ni mọto naa ti gbina lojiji, tina jo eeyan mẹrin pa ninu awọn mẹrinla to wa nibẹ.
Lasiko ta a pari iroyin yii, ko ti i sẹni to mọ ibi ti awọn mẹwaa yooku wa, boya wọn ku ni tabi wọn sa wọgbọ. Ṣugbọn Akinbiyi lawọn ko gburoo wọn, awọn to jona ku nikan lawọn ri. Koda, nọmba ọkọ yii paapaa ko ṣee mu, nitori o jona raurau ni.
Teṣan ọlọpaa Ogbere ni ẹjọ naa wa bayii gẹgẹ bi Akinbiyi ṣe wi, wọn si ti mu dẹrẹba to wa tanka epo to n jo naa ju si gbaga.