Lẹẹkan si i: Awọn agbaagba Yoruba tun binu si Tinubu

Ohun ti ibo ọdun 2023 yoo da silẹ, paapaa laarin awọn aṣaaju Yoruba yikayika, ko sẹni to ti i le sọ rara ni. Bi awọn aṣaaju Yoruba kan ti n sọ pe awọn ko fẹ Naijiria mọ, awọn ko tilẹ duro de ibo ọdun 2023, ki wọn ṣaa jẹ ki Yoruba maa lọ, nitori iya to n jẹ wọn ni Naijiria yii ti pọ ju, bẹẹ lawọn mi-in n sọ pe ko ṣee ṣe bẹẹ, ki wọn jẹ ka duro ki a le tun nnkan ṣe, ka si ṣeto lati jẹ anfaani to ba tọ si wa ni Naijiria ni. Lara awọn ti wọn n mura si eto pe ki Yoruba ya kuro lara Naijiria ni awọn ẹgbẹ to ko gbogbo awọn ẹgbẹ oriṣiiriṣii nilẹ Yoruba sinu, ẹgbẹ Yoruba World Congress (YWC). Ẹgbẹ naa ti Ọjọgbọn Banji Akintoye jẹ aṣaaju wọn ti gbe ọpọlopọ igbesẹ lati ri i pe kinni naa yoo ṣee ṣe bẹẹ, Yoruba yoo kuro lara Naijiria o pẹ o ya ni. Igbagbọ tiwọn ni pe ko si ohun ti Yoruba le ṣe ni aṣeyege bi wọn ba wa lara Naijiria yii, afi igba ti wọn ba too jade.

Ẹgbẹ naa ko mu ọrọ naa ni kekere, bi ko si jẹ ti ija to de laarin awọn agbaagba ẹgbẹ naa lọsẹ meji sẹyin bayii, ti awọn kan ni awọn lawọn lẹgbẹ, ki i ṣe Banji Akintoye, ṣugbọn ti awọn mi-in ni ẹgbẹ Akintoye ni, awọn lawọn si fi i ṣe aṣaaju awọn, awọn iwe ti ẹgbẹ naa n to iba ti jade si gbangba. Ki ija too de yii, wọn ti lọ sinu ajọ orilẹ-ede agbaye kan ti wọn n pe ni UNPO, wọn si ti fi orukọ Yoruba sinu ẹgbẹ naa, wọn ni awọn yoo ko Yoruba jade ni Naijiria laipẹ rara. Ṣugbọn awọn kan ko fara mọ ọn, paapaa awọn oloṣelu asiko yii, awọn ti wọn wa ninu ẹgbẹ APC to n ṣejọba, ẹni to si ṣaaju wọn ni Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu. Ibi ti oju Tinubu wa bayii ni ibi ibo aarẹ ti wọn yoo di ni ọdun 2023, ilakaka rẹ si ni bi yoo ti le dari ironu awọn oloṣelu ilẹ Hausa si ọdọ ara rẹ, ti wọn yoo fi gba lati gbe ijọba naa fun un.

Ọjọgbọn Banji Akintoye

Nidii eyi, Tinubu ko fẹ awọn ọrọ kankan to le di oun lọwọ, tabi to le mu awọn Hausa bẹrẹ si i ronu pe ti wọn ba gbejọba foun, awọn Yoruba loun yoo fi ijọba naa sin, tabi pe oun yoo fa Naijiria le Yoruba lọwọ, gẹgẹ bi awọn ti wọn n ṣejọba bayii ti fa Naijiria le awọn Hausa-Fulani lọwọ. Ohun ti Tinubu ko ṣe da si iru ọrọ bẹẹ mọ niyi, igba mi-in si maa n wa to maa n sọrọ lati fi ta ko awọn ti wọn ba n leri pe awọn yoo kuro ni Naijiria dandan. Nibi ti ibinu awọn agbaagba Yoruba ti bẹrẹ si Tinubu ọhun ree. Awọn agbaagba yii n binu pe lara awọn ni Tinubu wa tẹlẹ ko too di pe ẹgbẹ oṣelu APC gbajọba, ati ko too di pe oun naa bẹrẹ si i mura lati du ipo aarẹ Naijiria, wọn ni ọpọ igba lo ti nawo, to si nara, lati jẹ ki Yoruba mọ ọna ti wọn yoo gba jade ni Naijiria, nitori oun naa mọ pe ohun ti oju awọn Yoruba n ri lorilẹ-ede yii ko dara.

Loootọ si ni, igba kan wa ti Tinubu sọ ọ jade pe oun ko nigbagbọ ninu iṣọkan tabi Naijiria ẹyọ kan, to ni ki onikalulu maa ṣejọba tirẹ lọtọọtọ ni yoo dara.  Ninu iwe iroyin This day lo ṣorọ naa si ninu oṣu kẹrin, ọdun 1997. O ni ko sohun to n jẹ Naijiria, Yoruba ko si le ṣe Naijiria, ohun to ti dara ju ni ki kaluku maa ṣe tirẹ lọtọọtọ, nitori baba ẹgbẹ mọ iye ọmọ rẹ, Yoruba ki i ṣe Hausa, Hausa ki i ṣe Yoruba, ọtọọtọ la rin wa, bẹẹ ni ede ati aṣa wa ko jọ ara wọn. Ọsẹ to kọja yii lawọn kan ju ọrọ naa jade nibi ti Tinubu ti sọ ọ, ẹnu si ya awọn eeyan pe ṣe Tinubu to n sọrọ bayii pe ko si meji Naijiria ti figba kan sọ pe ko si ohun to n jẹ Naijiria, n lawọn eeyan ba bẹrẹ si i bu u sori ẹrọ ayelujara, wọn ni ko si ohun ti awọn oloṣelu yii ko le ṣe nibi ti wọn ba ti n ri ounjẹ jẹ, pe igba ti Tinubu ko ti i ri owo oṣelu lo ṣe n sọ bẹẹ, o ti ri owo bayii ko fẹ ki Yoruba bọ loko ẹru.

Awọn kan lọ si ori ẹrẹ ayelujara yii ti wọn n ṣepe, ti wọn n pe ayajọ le awọn ti wọn ko fẹ ki Yoruba bọ kuro labẹ ajaga ti wọn wa yii, iyẹn ajaga Naijiria, ti wọn n sọ bi yoo ti ri fun wọn pẹlu aṣẹ lẹnu wọn. Bẹẹ ni ọpọlọpọ oko ọrọ ti awọn eeyan yii n ju yii, Tinubu ni wọn n juko si, nitori wọn nigbagbọ pe oun ni ko fẹẹ jẹ ki awọn Yoruba lọ, to n lẹdi apo pọ pẹlu awọn ti wọn n mu Yoruba lẹru.

Ni ọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, ni ọrọ naa waa burẹkẹ. Nibi ipolongo ibo ti wọn ṣe fun Arakunrin Rotimi Akeredolu ni Akurẹ, ipinlẹ Ondo ni. Akeredolu n dupo gomina ibẹ lẹẹkeji, awọn ti wọn si n ba a fa kinni naa le pupọ, n loun naa ba mura si ipolongo. Lati fi han pe gbogbo aye lo wa lẹyin oun, ati awọn agbaagba APC, o ni ki gbogbo wọn maa bọ niluu Akurẹ, ki wọn waa sọ fawọn ara Ondo pe toun lawọn n ṣe.

Ohun to gbe Tinubu de Ondo ni Satide naa ree. Ọjọ naa ni APC  ṣi polongo rẹ nibẹ, ero si pọ lọ biba lati fihan Akeredolu pe ko sewu loko, afi giri aparo. Nibẹ ni Tinubu ti bẹrẹ si i bọ, fun igba akọkọ ni gbangba, o sọ ootọ diẹ, ṣugbọn o fi ọpọlọpọ ọrọ sinu ti ko sọ, eyi si bi awọn agbaagba ilẹ Yoruba ninu ju lọ. Nibi to ti n kampeeni, Tinubu fihan pe oun mọ pe irẹjẹ wa ninu eto bi wọn ti n pin awọn ohun-ini Naijiria, nitori ọna to yẹ ki awọn ipinlẹ ilẹ Yoruba wa ni bi wọn yoo ti ṣe e ti ijọba apapọ Naijiria yoo fi maa pin ọrọ ati ohun-ini apapọ ni ọna to dara ju lọ. Ọna wo lo dara ju lọ? Tinubu ko ṣalaye, bẹẹ ohun to n da ija silẹ laarin awọn ipinlẹ Yoruba ati ijọba Naijiria gan-an niyi. Ohun to n fa irẹjẹ ni, irẹjẹ yii lo si n bi awọn Yoruba ati Ibo ninu.

Oloye Ayọ Adebanjọ

Ọna to dara ju lọ ko ju ki wọn pin ohun-ini Naijiria bi kaluku ba ti n da si i to: ki wọn pin owo Naijiria bi kaluku ba ti n pawo fun Naijiria to. Bi ipinlẹ kan ba pa naira mẹwaa, ki wọn foun ni aadọta, ki awọn to ku pin aadọta to ku; ki i ṣe ki ipinlẹ kan pa naira mẹwaa, ki wọn pin naira mẹjọ owo naa fun awọn ti wọn ko pa owo lọdọ wọn, ki wọn waa fun ipinlẹ to pawo naa ni naira kan tabi meji, ki wọn ni nitori awọn tọhun pọ ju wọn lọ ni. Ohun ti wọn ṣe n pariwo atunto ree, ti wọn ni ki ijọba tun eto pinpin ọrọ Naijiria to, pe ohun kan ṣọsọ to le mu ifọkanbalẹ ati ajọṣe to daa wa niyi, ki i ṣe ki inaki maa le ọgẹdẹ, ki ọbọ maa ṣereka, ki ọgẹdẹ gbo tan, ki ọbọ waa fi kinni naa jẹ. Ohun ti wọn n pe ni atunto niyi, ohun ti wọn si ti n pariwo lati ọjọ yii wa ree, ti awọn agbaagba Yoruba yii fi ni ti ko ba ti si atunto, awọn yoo fi Naijiria silẹ ni.

Ninu ipade ti wọn ṣe ni Abuja ni 2014, iyẹn ipade apero ofin ilẹ wa, nibẹ ni wọn ti kọkọ sọrọ atunto yii fun ijọba Jonathan, ti awọn Buhari ati APC si fi i sinu ipolongo wọn pe ohun ti awọn yoo ṣe niyi, ko too waa di pe wọn gbajọba tan, wọn ko ya si i. Bẹẹ, ọrọ ti Tinubu sọ ni Ondo yii, ọrọ atunto ni, atunṣe si eto bi a ṣe n pin nnkan. Ohun to si n dun awọn agba Yoruba yii ree, Baba Ayọ Adebanjọ sọrọ, bẹẹ ni Yinka Odumakin ati awọn agba mi-in bẹẹ, wọn ni ki Tinubu ma fi ọrọ si ẹgbẹ ẹnu sọ mọ, bo ba fẹẹ ṣe Yoruba, ko ṣe Yoruba ki gbogbo aye mọ pe Yoruba ni, bo ba si fẹẹ ṣe Hausa ko ṣe Hausa, ki gbogbo aye kuku mọ pe Hausa lo ba lọ. Ohun ti awọn ko ni i fẹ laarin awọn ni adan ti ko ṣeku ti ko ṣẹyẹ. Wọn ni aṣaaju ẹgbẹ APC ni Tinubu, o si lẹnu ninu ẹgbẹ naa, eyi to n sọ ni Ondo yii, laarin awọn aṣaaju ẹgbẹ rẹ ti wọn n ṣejọba lo yẹ ko ti sọ ọ, ki wọn si ṣe ohun ti Naijiria fẹ fun wọn.

Ko jọ pe ọrọ naa tẹ Tinubu lọrun, nitori awọn ọmọ ẹyin rẹ ni ko le sọ ju bẹẹ lọ, pe to ba sọ ju bẹẹ lọ, yoo di ọta awọn ara Oke-Ọya, ilakaka rẹ lati di aarẹ ni 2023 yoo si fori ṣanpọn.

Leave a Reply