Lekan Balogun lo dagba ju ninu awa agba ijoye Ibadan,  ṣugbọn mi o lagbara lati sọ ẹni to maa jọba-Ladọja

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan, Sẹnetọ Rashidi Adewolu Ladọja, to tun jẹ Osi Olubadan tilẹ Ibadan ti sọ pe oun ko lagbara lati sọ ẹni to yẹ ko gori itẹ Olubadan lẹyin ipapoda Olubadan ana, Ọba Saliu Akanmu Adetunji.

Eyi lo  ta ko iroyin kan to n ja ran-in-ran-in kiri bayii pe Ladọja ti gba pe Sẹnetọ Balogun lẹni naa to yẹ ko bọ sori itẹ Olubadan bayii.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹfa, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022, l’Agba-Oye Ladọja sọrọ naa lasiko to n gbalejo ẹni to n ṣoju ẹkun idibo Aarin Gbungbun ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin agba ilẹ yii niluu Abuja, Sẹnetọ Teslim Fọlarin atawọn agba ẹgbẹ oṣelu APC to kọwọọrin pẹlu ẹ nile ẹ (Ladọja) to wa laduugbo Bodija, n’Ibadan, lati ki i ku arafẹraku Olubadan to waja ọhun.

Lasiko abẹwo yii ni wọn ti beere lọwọ Ladọja pe ta lo yẹ ko jẹ Olubadan bayii pẹlu gbogbo awuyewuye to n lọ nigboro nipa ẹni ti ipo naa tọ si, ti baba naa ṣi fesi pe oun ko lagbara lati sọ ẹni tipo Olubadan kan.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Fun anfaani awọn to n beere, ko ruju rara, Ẹgbọn Lekan Balogun lo ga ju lori akaba oye, awọn naa ni wọn kangun sipo Olubadan. Ṣugbọn mi o lagbara lati fi ẹnikẹni jọba, gomina ipinlẹ yii nikan lo lagbara lati fi ẹni ti ọba ba tọ sí jọba.

“Nigba ti Ajimọbi (gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ) ṣatunṣe ti ko wulo si ọrọ oye Ibadan, o fẹẹ jẹ pe gbogbo awa agba ijoye Ibadan la o fara mọ igbesẹ yẹn, ta a si tori ẹ pe Gomina Ajimọbi lẹjọ si kootu. Amofin Michael Lana ni lọọya ta a gbeṣẹ yẹn fun nigba yẹn.

“Nigba to ya l’Amofin Lana pe mi pe awọn kan ninu wa ti pe oun pe awọn o ṣẹjọ mọ, ki oun yọ orukọ awọn kuro ninu ẹjọ naa, o ba ku emi ati Ẹgbọn Balogun nikan. Ọsẹ meji lẹyin iyẹn l’Ẹgbọn Balogun naa pe mi pe awọn naa ko ṣe mọ. Mo waa pe Amofin lana pe ṣe emi nikan le ma ba ẹjọ yẹn lọ, o si ni bẹẹ ni. Idi niyẹn to ṣe jẹ pe emi nikan lo ku ti mo ta ko atunṣe ti Gomina Ajimọbi ṣe si ọrọ oye jijẹ ninu awa agba ijoye nigba naa.

“Awa nile-ẹjọ da lare lori ẹjọ yẹn. Ajimọbi pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ta ko idajọ yẹn. Ọ ku diẹ ki Ajimọbi fi ipo gomina silẹ nile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun da ẹjọ yẹ pada sile-ẹjọ gíga pe ki wọn tun ẹjọ yẹn gbọ latibẹrẹ.

“Nigba ti ẹjọ yoo fi bẹrẹ pada nile-ẹjọ giga, Makinde ti depo gomina, o si sọ pe oun ko fẹ ẹjọ ni toun, lo ba ni ka gbe ẹjọ kuro ni kootu, ka yanju ẹ nitubi-inubi laarin ara wa. Gbogbo wa la si fara mọ ọn, ta a si ṣe bi gomina ṣe wi.

 

“Lẹyin ta a ti pari ọrọ yẹn laarin ara wa, a fi igbesẹ yii to ile-ẹjọ leti, ohun ti idajọ gbogbo awọn adajọ yẹn fẹnu ko le lori ni pe a ti yanju ọrọ yẹn ni ibamu pẹlu awọn ilana kan.”

Pataki ninu awọn ilana ọhun gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ni pe awọn agba ijoye wọnyi ko ni i pe ara wọn lọba mọ, debii pe wọn yoo tun de ade lọ sibikibi ti wọn ba n lọ.

Ladọja tẹsiwaju ninu ọrọ ẹ pe lẹyin-o-rẹyin ni wọn (awọn agba ijoye yooku) tun pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun pe awọn ko fara mọ idajọ yẹn. Ẹjọ meji ọtọọtọ ni wọn si tun gbe dide nitori ọrọ yii, ẹjọ mejeeji ṣi wa ni kootu di bi mo ṣe n sọrọ yii.

“Nitori naa, mo fẹ ki gbogbo aye mọ pe mi o da wahala kankan silẹ lori ọrọ to ni i ṣe pẹlu ẹni to yẹ ko jẹ Olubadan. Awuyewuye ti ko nitumọ lọrọ yii n da silẹ. Awọn to pẹjọ lo yẹ kawọn eeyan sọ fun pe ki wọn gbe ẹjọ ti wọn pe kuro ni kootu.”

Ni ibamu pẹlu ilana ti wọn fi n jọba ilu naa, Sẹnetọ Balogun, to tun jẹ Ọtun Olubadan lọwọlọwọ, ni gbogbo aye gba pe o kan lati jọba Ibadan tuntun.

Ṣugbọn nigba ti agba agbẹjọro ọmọ Ibadan nni, Amofin Michael Fọlọrunṣọ Lana, kọ lẹta si Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti i ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ lati ma ṣe ti i fi Olubadan tuntun jẹ nitori ẹjọ to wa ni kootu, eyi ti Sẹnetọ Balogun atawọn agba ijoye Ibadan mi-in n ba ijọba ipinlẹ yii fa lọwọlọwọ lori ọrọ oye ọba ti ijọba ipinlẹ yii, lasiko Gomina (Oloogbe) Abiọla Ajimọbi fawọn agba ijoye Ibadan yooku jẹ yatọ si Ladọja.

Amofin Lana ni bi gomina ko ba ni suuru ki igbẹjọ ọhun wa sopin na, bo ba yara fẹnikẹni jọba Ibadan bayii, o le kọrun bọ wahala ẹjọ mi-in ni kootu.

Latigba naa lawuyewuye si ti gba igboro kan, pe Ladọja lo ran agba amofin naa niṣẹ to jẹ yii, nitori to fẹẹ kanju gori itẹ bo tilẹ jẹ pe ipo kẹta lo wa bayii lori atẹgun sipo ọba.

Ṣugbọn Agba-Oye Ladọja sọ pe oun ko ran lọọya naa niṣẹ nitori oun pẹlu ẹ ko foju kanra, bẹẹ lawọn ko jọ sọrọ lati bii oṣu meloo kan sẹyin.

Ọrọ ti Osi Olubadan sọ yii lo fidi awijare Amofin Lana mulẹ ninu ifọrọwọrọ to ṣe pẹlu ALAROYE lọjọ Iṣẹgun, Tusidee ọsẹ yii.

Tẹ o ba si gbagbe, lọjọ Aiku, ọsẹ yii, iyen, Sannde, ọjọ keji, oṣu kin-in-ni, ọdun 2022 yii, ni iku sọ Saliu Akanmu Adetunji kalẹ lori apere ọba.

Agba amofin naa ṣalaye pe lẹta ti oun kọ si gomina ki i ṣe lati gbe lẹyin ẹnikẹni, bi ko ṣe lati gba gomina nimọran ko ma baa gbe igbesẹ to le mu ko yaju si ẹka eto idajọ ilẹ yii tabi ko di ohun ti awọn kan yoo tun maa pe ijọba lẹjọ lori ọrọ oye Olubadan.

 

Leave a Reply