L’Ekiti, adajọ ran olukọ fasiti lẹwọn, ọmọ kekere lo fipa ba lo pọ

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ Majistreeti ipinlẹ Ekiti to wa niluu Ado-Ekiti, ti ran olukọ agba kan nileewe giga naa, Dokita Kayọde Samuel, lẹwọn pẹlu ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mejila lo pọ.

Ọkunrin ẹni ọdun marunlelaaadọta (55) ọhun jẹ olukọ ni eka ede oyinbo nileewe giga Yunifasiti ipinle Ekiti, (EKSU), bẹẹ lo tun jẹ pasitọ ni ijọ igbalode kan, Shepherd of the Foursquare Gospel, to wa niluu Ado-Ekiti.

Ṣaaju ni ọkunrin kan to jẹ oṣiṣẹ sifu difẹnsi, Iyaniwura Oluwanifẹmi, ti gbe olukọ yii lọ sile-ẹjọ, ki kọmiṣanna eto idajọ nipinlẹ Ekiti too tẹwọ gba ẹjọ yii lorukọ ipinlẹ naa.

Ninu iwe ẹsun ọhun ni wọn ti sọ pe Dokita Samuel fipa ba ọmọ ọdun mejila ti oun atawọn obi rẹ jọ n gbe ni ayika ile kan naa pẹlu rẹ lo pọ niluu Ado-Ekiti lọdun to kọja.

Awọn obi ọmọdebinrin yii sọ pe ẹsun naa ko ri bẹẹ, wọn ni irọ ni ọmọ awọn n pa, ati pe ootọ ni dokita yii sọ pe oun ko ba a lo pọ. Wọn ni alaaanu awọn ni olukọ yii, nitori o maa n ṣe oore fun mọlẹbi awọn ni gbogbo igba tawọn ba wa ninu iṣoro.

Ṣugbọn ijọba ipinlẹ Ekiti, ti Kọmṣanna fun eto idajọ ati adajọ agba nipinle naa, Ọgbẹni Ọlawale Fapohunda, ṣoju fun sọ pe ijọba yoo ṣe ohun gbogbo lati ṣewadi to daju lori ẹsun naa.

Fapohunda fi kun ọrọ rẹ pe ẹsun ifipa ba obinrin ati awọn ọmọde lo pọ ti wọpọ laarin awọn olukọ ati awọn oluṣọagutan nipinlẹ naa. O ni ki ile-ẹjọ naa paṣẹ pe ki olukọ yii maa lọ si ọgba ẹwọn titi di igba ti iwadii yoo fi pari.

Ẹsun wọnyi lo juwe gẹgẹ bii ohun to lodi sofin, to si ni ijiya nla.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ Onidaajọ I.T Ọlaọlọrun fọwọ si ẹbẹ kọmiṣanna naa, o si paṣẹ pe ki olukọ naa maa lọ si ọgba ẹwọn.

Ẹyin eyi lo sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kẹtadilọgbọn, oṣu keje.

 

Leave a Reply