Lẹta pataki si awọn ọdọ ọmọ Yoruba (2)

Nigba ti a fẹẹ dibo ni ọdun to kọja, mo bẹrẹ si i pariwo ki wọn ma dibo fun Buhari. Ṣugbọn n ko deede sọ pe ki wọn ma dibo fun un o, mo ṣalaye kan fun gbogbo ọmọ Yoruba to ba n feti si mi. Alaye ti mọ ṣe nigba naa ni pe ẹni to ba dibo fun Buhari, ki i ṣe Bubari lo dibo fun, awọn kan ti wọn wa nitosi ẹ ti wọn n ba a ṣejọba ni. Mo la ọrọ mọlẹ gan-an nigba naa debii pe awọn kan n bẹru pe boya wọn aa gbe mi nitori awọn aṣiri ti mo tu. Bẹẹ mo tu awọn aṣiri yii ki gbogbo ọmọ Yoruba le mọ ohun to n lọ ni. Mo sọ ọ debii pe soku-daaye (ẹni to ti ku, ti wọn da pada saye) ni Buhari, mo ni ẹni to ba ni oun loun dibo fun fi kaadi ṣofo lasan ni. Mo ṣalaye fun wọn pe ọpọ nnkan lo n lọ ti Buhari ko mọ rara, ko tilẹ ye e, bẹẹ ni ko ba wọn da si i, nitori aiyaara rẹ ti gba ọpọ laakaye ara rẹ, ko si mọ pupọ ohun to yi i ka mọ.

Mo sọ fun awọn ọmọ Yoruba nigba ibo naa pe ti Buhari ba fẹẹ jade, wọn yoo mura fun un bii ẹni to n mura fun eegun ni, nitori wọn aa ko oriṣiiriṣii oogun si i lara, oogun ti yoo fi ṣiṣẹ fun bii wakati mẹta si mẹrin ki wọn too tun rọ́ ọ pada sinu ọkọ tabi sinu ẹronpileeni, ti wọn aa tun ko abẹrẹ mi-in bo o. Mo ni to ba jẹ ara Buhari ya ni, ko sohun ti ko le jẹ ki emi naa dibo fun un, nitori o ṣee ṣe ko jẹ awọn ti wọn yi i ka ni wọn n ba ijọba rẹ jẹ, bo ba si wọle lẹẹkeji, o yẹ ko le tun ijọba naa ṣe pada. Awọn ti wọn sun mọ mi paapaa ni ki i ṣe pe Buhari lo buru to bẹẹ, pe awọn eeyan kan ti wọn sun mọ ọn ni wọn n sọ ijọba rẹ lorukọ buruku. Awọn bii Kyari, bii Daura, bii Funtua, atawọn agbẹyin-bẹbọ-jẹ mi-in ti wọn yi i ka nile ijọba. Mo sọ fun wọn pe emi naa ti ronu eyi, tori mo mọ ohun to ṣe nigba to ṣejọba ni 1984 si 1985.

Ṣugbọn ni 2019, mo sọ fun wọn pe Buhari ti yatọ, aiyaara ti gba gbogbo aapọn ati wahala yoowu to le ṣe kuro lara ẹ. Aiyaara yii lo si fi n ba nnkan jẹ, ko si le tun nnkan kan ṣe. Mo ronu pe bi Buhari ba gbe aiyaara yii pada sile ijọba lẹẹkeji, ohun ti yoo bajẹ fun Naijiria ko ni i ṣee tunṣe laarin ogun ọdun to ba gbejọba naa silẹ. Mo ṣalaye pe bi Buhari ba daa, ara rẹ ko daa, aisan ti gba alaafia ara ẹ kuro, ẹni ti ara rẹ ko ba si ya, ko sohun to le ṣe, nitori agbara ni yoo ṣaa fi ṣe iṣẹ ijọba to ba fẹẹ ṣe. Awọn alaye ti mo ṣe nigba naa niyi; mo tun mu wọn wa si iranti ka le mọ pe gbogbo ohun to n ṣẹlẹ bayii ko jẹ tuntun. Ṣugbọn gegẹ bi iṣe wa, awọn eeyan he mi ni, ti wọn n sọ oriṣiiriṣii ọrọ si mi. Ẹlomi-in ni ki lo de ti mo n fi Buhari ṣe yẹyẹ nitori aiyaara rẹ, pe ṣe emi ro pe aisan ko le ṣe mi ni. Awon mi-in gan-an n ṣepe pe ohun ti yoo ṣe mi yoo buru ju ti Buhari yii lọ bi n ko ba jawọ ninu ọrọ ẹ.

N ko jawo lọrọ ẹ titi doni, bẹẹ ni ko sohun to ṣe mi; nitori ohun ti mo n sọ fawọn eeyan wa nigba naa, ododo ọrọ gbaa ni. Eeyan lo maa n ro pe olododo aa ku sipo ika, Ọlọrun ko ri bẹẹ rara. N ko binu Buhari nitori nnkan mi-in ju pe ara rẹ ko ya, ati pe aiyaara to n ṣe e ti ko ba wa debii pe ko bikitia mọ bi wọn ba ta iran Yoruba sinu oko ẹru. Boya oun lo n ṣe e, boya awọn kan ni, mo ṣaa mọ pe ohun ti wọn ṣe ko dara, ati pe bi ara rẹ ba ya ni, oun naa ko ni i fẹẹ gba orukọ buruku iru eyi, ko si ni i ro pe ohun kan ti oun le ṣe fun Naijiria ni lati lu u fọ. Eebu igba naa pọ, nitori ọrọ ki i ye awọn eeyan wa: wọn yoo maa bu ọ, wọn yoo maa ṣepe, ara wọn yoo si maa gbona lori ohun ti wọn ko mọ rara. Bi wọn ṣe ṣe bi ere bi ere ti wọn gbe Buhari wọle lẹẹkeji niyi, eyi tawọn Yoruba tiwa si ṣe ninu ọrọ  yii lo n jẹ oun.

Nitori bẹe, nigba ti mo gbọ pe Buhari kọru, to loun o ni i yọju sawọn aṣofin, ti awọn minisita rẹ kan si n din irọ ni robo, ẹrin ni mo n rin ni temi. Ohun to n pa mi lẹrin-in ni pe nigba ti wọn ti sọ fun mi pe awọn aṣofin n pe e ni mo ti sọ fawọn to wa lẹgbẹẹ mi pe Buhari ko ni i yọju. Awọn yii ni nitori kin ni, won ni ṣebi anfaani yoo wa fun un lati waa sọ ohun gbogbo tijọba ẹ ti ṣe faraalu ni, aa si beere fun iranlọwọ awon eeyan ki a le ṣẹgun Boko Haram. Mo ni ki i ṣe Buhari ti emi n wo yẹn lo maa yọju si wọn, nitori yiyọju ti iba yọju yii maa tu gbogbo ohun to n run nilẹ latọjọ yii wa sita ni. Mo ni bi Buhari ba yọju, itiju lo maa ba kuro nibẹ, nitori awọn ti wọn n pakeeji ẹ, awọn ti wọn n yi aṣọ mọ ọn lori ninu ooru, ti wọn n gun un labẹrẹ amarale, ti wọn n bo gbogbo ẹ mọlẹ lai jẹ ki araalu ri i, aṣiri awọn naa maa tu niyẹn, bi aṣiri Buhari ba ti tu.

Awọn to wa lẹgbẹẹ mi nijọ naa, bo tilẹ jẹ ọmọwe ni gbogbo wọn ko gba ọrọ yii gbọ, wọn ni Buhari yoo yọju, nitori pe mi o fi taratara gba tiẹ ni mo ṣe ro pe ko le yọju sawọn aṣofin. Ṣugbọn nigba ti ọrọ ri bo ti ri, tẹnikan o ri Buhari, ti a ko si gbohun ẹ, awọn eeyan naa pe mi pe ọrọ ti mo wi ṣẹ, ṣugbọn ohun to n ṣẹlẹ ya awọn lẹnu. Koko to wa nibẹ ni pe Buhari kọ lo n ṣejọba Naijiria, loootọ orukọ ẹ lo wa nibẹ bii Aarẹ. Ara rẹ ko ya, awọn kan n bo o mọlẹ ni, wọn n lo orukọ ẹ lati ṣe aburu gbogbo. Awon Yoruba to wa nibẹ ko le sọ, wọn kan maa n fẹsẹ janlẹ ni kọrọ yara wọn pe wọn o jẹ ki awọn ri Buhari ni. Awon Ibo to wa nibẹ ko jẹ gbin, nitori bi awọn ko ti ri Buhari tẹ wọn lọrun, o n jẹ ki wọn ṣe gbogbo ibajẹ ti wọn ba fẹẹ ṣe. Awọn Hausa-Fulani ti wọn mọ ko pọ, bi gbogbo awọn yẹn tiẹ mọ, ko ṣeni ti yoo wi nnkan kan.

Ohun ti mo ṣe n tẹnu mọ ọrọ ewu to wa ninu ọrọ Naijiria yii niyẹn. Nigba ti bọọsi kan wa ni gareeji, tawọn agbero n pero sinu ẹ, ti wọn pero naa ti bọọsi kun bamu, ti wọn gba owo, ti wọn ni ki wọn maa lọ, ti dẹrẹba sare ko siwaju mọto, to tẹna, ti mọto si n lọ, ṣugbọn ti awọn ero ko mọ pe afọju lo n wa mọto naa. O ti wa mọto kuro ni gareeji ki wọn too mọ pe afọju ni, ti kọndọkitọ ẹ waa n fawọn eeyan lọkan balẹ pe aa gbe wọn debi ti wọn n lọ, nitori bo ba diju pata gan-an paapaa, ko sibi ti ko mọ loju ọna ti awọn n gba lọ. Oponu wo ni ko waa mọ pe ijamba ni yoo kẹyin iru irin-ajo bẹẹ, nitori nigba ti ọkunrin naa ba wa mọto ọhun sẹnu tirela, ko sẹni kan ti yoo ye ninu wọn. Afọju lo n wa mọto ijọba Naijiria lọ bayii, ohun to si buru ni pe eti ọkunrin dẹrẹba naa ti tun n di, nigba wo ni ko ni wa wa si koto!

Nnkan yoo ṣelẹ ni Naijiria, bo ba jẹ bayii lawọn ti wọn n ṣejọba wa ṣe n ṣe e lọ. Nnkan yoo ṣẹlẹ, ko si le pẹ rara. Ṣugbọn ohun yoowu to ba fẹẹ ṣẹlẹ, ẹru Yoruba lo ba mi ju lọ. Lojoojumọ ni iyapa, ainisọkan, ọtẹ, tẹmbẹlẹkun aarin awọn agbaagba wa n pọ si i. Ohun ti mo si ṣe sọ lọṣẹ to kọja pe asiko naa ti to ki awọn ọdọ gba nnkan wọn kuro lọwọ awa agba ti a ti ta, ti a ti ra, tan yii; ki wọn mọ bi wọn yoo ṣe tun aye iran tiwọn ṣe. Awọn Awolọwọ lo gbajọba mọ awọn agbaagba Yoruba ti wọn n ṣe e tẹlẹ lọwọ, awọn ti wọn wa ni abẹ ọmburẹla oyinbo, ti wọn jọ n pawọ-pọ rẹ wa jẹ. Awọn Awolọwọ, Akintọla, Bode Thomas, ati awọn ẹlẹgbẹ wọn ti wọn ja ija naa, wọn ṣẹṣẹ le ni ọmọ ọgbọn ọdun ni, nigba ti wọn si fi maa pe ọmọ ogoji ọdun, ijọba ti bọ si ọwọ wọn. Bawo ni wọn ṣe ṣe e? Alaye ti a oo ṣe lọsẹ to n bọ ree, ki awọn ọdọ asiko yii le mu eyi lo, nitori ọjọ n lọ o.

Leave a Reply