Lẹyin bii ọsẹ meji ti wọn ti n wa a, wọn ba oku Jọkẹ nihooho ninu igbo labule Atoyọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti bẹrẹ iwadii lori ohun to  ṣokunfa iku obinrin ẹni ọdun marundinlọgọta kan, Oloogbe Jọkẹ Ọlaniji, ẹni ti wọn ri oku rẹ ninu igbo lẹyin ọsẹ meji ti wọn ti n wa a labule Atoyọ, nijọba ibilẹ Ila Oorun Ondo.

Iya oloogbe ọhun, Julianah, ni oun ko si nile lasiko ti ọmọ oun jade nile ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan ọjọ ti awọn ri i gbẹyin.

O ni iyalẹnu lo jẹ foun lati ri ilẹkun yara rẹ to ṣi silẹ gbaragada nigba toun pada wọle lọjọ naa, ṣugbọn ti oun ko ri oun funra rẹ.

Igba to reti rẹ titi ti ko ri i ko pada wale lo bẹrẹ si i wa a kaakiri abule, ibi to ti n daamu lori bo ṣe fẹẹ ri obinrin ọhun lo ni awọn ara abule kan ti sọ foun pe awọn ri i nigba to n jade nile, ti wọn si ro pe gala tabi ọra lo fẹẹ lọọ ra.

Lẹyin ti wọn ti gbiyanju titi, ṣugbọn ti wọn ko rẹni to jọ ọ ni wọn sẹsẹ lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa tesan Bọlọrunduro leti.

Abilekọ Julianah ni ọjọ Isẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, lawọn ọlọpaa kan waa ba oun nile pe awọn ti ri oku ọmọ oun ninu oko koko kan ti ko jinna si ile wọn.

Ihooho ọmọluabi lo ni wọn ba oku rẹ, to si ti n jẹra mọlẹ.

Iya arugbo ọhun bẹ awọn ọlọpaa ki wọn ri i daju pe wọn ṣawari awọn to pa ọmọ oun, ki wọn si fi iya to tọ jẹ wọn labẹ ofin.

Leave a Reply