Lẹyin bii osu meji to kọwe fipo silẹ, Abegunde ti tun pada sọdọ Akeredolu

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Iyalẹnu nla lo jẹ fawọn eeyan nigba ti akọwe ijọba ipinlẹ Ondo ana, Ọnarebu Sunday Ifedayọ Abegunde, tun deedee yi ohun pada biri lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ ta a wa yii, to si ni Gomina Rotimi Akeredolu loun fẹẹ ṣiṣẹ fun lasiko eto idibo to n bọ yii.

Ọrọ ọkunrin tawọn ololufẹ rẹ n pe ni Abẹna yii ko si yatọ si ti ọmọ oni inakunaa inu Bibeli to binu kuro nile baba rẹ, ṣugbọn to tun pada waa bẹbẹ lẹyin bii osu diẹ to ṣe ohun gbogbo to ni basubasu.

Nnkan bii osu meji sẹyin ni Abegunde binu kọwe fipo silẹ lori ẹsun to fi kan Arakunrin nigba naa pe oun atawọn ẹbi rẹ nikan ni wọn n da ṣejọba ipnilẹ Ondo.

O ni ṣe ni gomina ọhun pa oun ti, to si kọ lati fun oun lawọn owo kan to tọ si ọfiisi oun gẹgẹ bii akọwe ijọba ipinlẹ.

Lẹyin eyi ni aṣofin tẹlẹ ọhun tun lọ sori redio aladaani kan niluu Akurẹ, nibi to ti sọ fawọn eeyan pe Aketi kọ lo wọle ninu eto idibo ti wọn di lọdun 2016, o ni eru ni wọn ṣe fun un to fi jawe olubori nigba naa.

Nigba ti ariwo ọrọ yii fẹẹ maa pọ ju pẹlu bawọn ọmọlẹyin gomina ṣe fi dandan le e fawọn agbofinro lati fi panpẹ ofin gbe e lori ohun to sọ lo sare yi ohun pada, to si ni ṣe lawọn eeyan ṣi oun gbọ.

O ni ohun ti oun sọ ni pe iṣẹ ti oun ṣe fun Akeredolu ṣaaju ati lasiko idibo naa lo jẹ ko rọwọ mu.

Agbo oṣẹlu Ṣegun Abraham lo kọkọ sa lọ, lẹyin ti iyẹn loun ko dije mọ lo tun fo fẹrẹ, o di ọdọ Ọlayide Adelami toun naa n dije pẹlu Aketi labẹ asia APC.

Alẹ ọjọ Aiku, Sannde, lọkunrin ọmọ bibi ilu Akurẹ naa ko gbogbo ọrọ to ti sọ nipa ọga rẹ tẹlẹ yii jẹ pẹlu bo tun ṣe pada sọdọ rẹ, to si ni oun nikan lo ku toun fẹẹ ṣiṣẹ fun ninu eto idibo ọjọ kẹwaa, osu kẹwaa, ọdun 2020.

Leave a Reply