Lẹyin idajọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, wọn tun ti geeti mọ awọn aṣofin mẹrin ti wọn yọ nipo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ṣe lọrọ ọhun da bIi ere ori itage l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, lasiko tawọn aṣofin mẹrin ti wọn yọ nipo fẹẹ fagbara wọ inu ọgba ile-igbimọ naa lẹyin tile-ẹjọ ko-tẹ-milọrun to wa niluu Akurẹ tun da wọn lare.

Ọgọọrọ awọn ẹsọ aabo la ri ti wọn ko ṣenu geeti ile igbimọ aṣofin ọhun lasiko t’ALAROYE ṣabẹwo sibẹ lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ko ṣeni ti wọn fun laaye ko wọle yatọ sawọn aṣofin kọọkan to wa si ọfiisi wọn.

Awọn aṣofin mẹrin ọhun, Irọju Ogundeji to jẹ igbakeji abẹnugan ile, Favour Tomowewo, Wale Williams ati Tọmide Akinribido ni wọn da duro ni nnkan bii oṣu diẹ sẹyin lori ẹsun titapa si ofin ati ilana ile.

Gbogbo awọn aṣofin wọnyi nile-ẹjọ giga to wa l’Akurẹ da lare ninu ẹjọ ọtọọtọ ti wọn pe ta ko bi wọn ṣe da wọn duro nigba naa.

Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, kan naa ni kootu ko-tẹ-milọrun to wa niluu Akurẹ tun da ẹjọ ti ile-igbimọ ọhun pe ta ko idajọ ile-ẹjọ giga nu, Onidaajọ Fọlayẹmi Ọmọlẹyẹ si pasẹ fun abẹnugan ile, Ọnarebu Bamidele Ọlẹyẹlogun, lati da wọn pada saaye wọn lẹyẹ-o-ṣọka.

Idajọ yii lo gbo awọn aṣofin naa laya ti wọn fi mu ọna ile-igbimọ ọhun pọn lọsan-an Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ṣugbọn ti wọn ko fun wọn laaye lati wọle.

Ọnarebu Irọju to gba ẹnu awọn ẹgbẹ rẹ sọrọ ni awọn adari ile ọhun ti huwa afojudi si aṣẹ ile-ẹjọ pẹlu bi wọn ko ṣe gba awọn laaye lati waa ṣe ojuṣe awọn lọfiisi tawọn eeyan dibo yan wọn si.

Nigba to n fun igbakeji abẹnugan ọhun lesi ọrọ rẹ, Ọnarebu Olugbenga Ọmọle tó jẹ alukoro ile-igbimọ ọhun ni ko ṣee ṣe ki wọn gba awọn aṣofin naa laaye lati wọle lai mu ẹda iwe idajọ tuntun naa lọwọ.

O ni ori ẹrọ ayelujara nikan lawọn ti n ka nipa idajọ ti wọn n sọrọ rẹ naa ki i ṣohun ti awọn si foju ri.

Leave a Reply