Adefunkẹ Adebiyi
Kiki ko ti i yee wọle fun wọn lẹyin igbeyawo, iyẹn awọn oṣere meji ti wọn ṣegbeyawọ loṣu kejila, ọdun to kọja, Lateef Adedimeji ati Adebimpe Oyebade. Ṣugbọn ni bayii, akọtun ti de ba oriire awọn tọkọ-taya yii, Adedimeji Lateef ti kọle olowo nla tuntun.
Rekete nile ọhun duro, awọn to si mọ bo ṣe n lọ sọ pe o ti ṣe diẹ ti ọdọmọde onitiata naa ti n ṣiṣẹ ile naa. Wọn ni ẹgbẹlẹgbẹ miliọnu lo fi gbele bii afin naa kalẹ.
N ni kiki oriire ba tun bẹrẹ si i wọle lọtun-un losi fun ọmọ bibi ilu Abẹokuta yii. Lati ọjọ Ẹti, Furaidee, to ti gbe fọto ile naa soju opo Instagraamu rẹ lawọn eeyan ti n ba a yọ, ti wọn n si n ṣadura pe ayọ ni wọn yoo fi gbele ọhun, agogo gbanjo ko ni i lu nibẹ.