Lẹyin iku Ṣẹrifa elepo, wọn tun ti ji dokita alabẹrẹ kan gbe l’Oke-Ogun

Aderounmu Kazeem

O fẹẹ jọ pe ojumọ kan wahala kan lawọn ajinigbe atawọn janduku afẹmiṣofo fi n ko idaamu ba awọn eeyan Oke-Ogun nipinlẹ Ọyọ pẹlu bi wọn ti ṣe ji Dokita alabẹrẹ kan, Akindele John Kayọde, gbe ni ileewosan kan nijọba ibilẹ apa Ariwa-Ibarapa.

Ọjọ Abamẹta, Satide, ni deede aago mọkanla alẹ ni wọn sọ pe wọn ji i gbe.

Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe ko ju bii wakati meloo kan ti awọn janduku afẹmi-ṣofo kan pa obinrin oniṣowo epo, Alaaja Sẹrifat Adisa, atawọn mọlẹbi ẹ meji kan niluu Idere, ni eyi naa tun ṣẹlẹ nipinlẹ Ọyọ.

Aago meje aṣalẹ ni wọn kọlu obinrin elepo yii atawọn aburo ẹ lọjọ keji ọdun tuntun niluu Idere, nijọba ibilẹ aarin gbungbun-Ibarapa.

Ni bayii, niṣe lawọn eeyan agbegbe naa n rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ ati ijọba apapọ wi pe ki wọn gba wọn kalẹ lori iku ojoojumo ati ijinigbe to n ṣẹlẹ lagbegbe ọhun bayii.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe oun yoo kan si awọn oniroyin ni kete ti oun ba ti gbọ ekunrẹrẹ bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye.

Leave a Reply