Aderounmu Kazeem
O fẹẹ jọ pe ojumọ kan wahala kan lawọn ajinigbe atawọn janduku afẹmiṣofo fi n ko idaamu ba awọn eeyan Oke-Ogun nipinlẹ Ọyọ pẹlu bi wọn ti ṣe ji Dokita alabẹrẹ kan, Akindele John Kayọde, gbe ni ileewosan kan nijọba ibilẹ apa Ariwa-Ibarapa.
Ọjọ Abamẹta, Satide, ni deede aago mọkanla alẹ ni wọn sọ pe wọn ji i gbe.
Ohun ti ALAROYE gbọ ni pe ko ju bii wakati meloo kan ti awọn janduku afẹmi-ṣofo kan pa obinrin oniṣowo epo, Alaaja Sẹrifat Adisa, atawọn mọlẹbi ẹ meji kan niluu Idere, ni eyi naa tun ṣẹlẹ nipinlẹ Ọyọ.
Aago meje aṣalẹ ni wọn kọlu obinrin elepo yii atawọn aburo ẹ lọjọ keji ọdun tuntun niluu Idere, nijọba ibilẹ aarin gbungbun-Ibarapa.
Ni bayii, niṣe lawọn eeyan agbegbe naa n rawọ ẹbẹ si ijọba ipinlẹ ati ijọba apapọ wi pe ki wọn gba wọn kalẹ lori iku ojoojumo ati ijinigbe to n ṣẹlẹ lagbegbe ọhun bayii.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ti sọ pe oun yoo kan si awọn oniroyin ni kete ti oun ba ti gbọ ekunrẹrẹ bi iṣẹlẹ ọhun ṣe waye.