Lẹyin isinmi ọlọjọ diẹ, awọn ọdọ tun jade fun ifẹhonuhan SARS l’Oṣogbo

Florence Babaṣọla

Lẹyin bii oṣu kan ti agbarijọpọ awọn ọdọ ti wọn n fẹhonu han ta ko ọrọ awọn ọlọpaa SARS kede pe awọn so iwọde naa rọ nipinlẹ Ọṣun, wọn tun ti bẹrẹ pada lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Ṣugbọn iwọde yii yatọ si bi wọn ṣe maa n ṣe e tẹlẹ, wọn to lọwọọwọ lọ sile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun lai di ẹnikẹni lọwọ rara, bẹẹ ni awọn mọto n kọja lọ.

Ọkan lara awọn aṣaaju awọn ọdọ naa ti wọn pe orukọ ara wọn ni Face of #EndSARS Movement, Emmanuel Adebisi, sọ pe ọrọ ti kuro ni ti awọn ọlọpaa SARS bayii, o ni oun tawọn n fẹ ni iṣejọba to duroo re, to si fi gbogbo araalu lọkan balẹ.

Adebisi ṣalaye pe ijọba gbọdọ ṣetan lati pese iṣẹ gidi fun awọn akẹkọọ-jade, ki aabo to peye si wa fun ẹmi ati dukia awọn araalu.

O fi kun ọrọ rẹ pe opin ti de ba asiko ti awọn oloṣelu yoo maa ṣeleri, ti wọn ko si ni i mu un ṣẹ fawọn araalu, wọn gbọdọ mọ pe agbara wa lọwọ awọn to yan wọn sipo.

Leave a Reply