Faith Adebọla
Bi gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa nni, Ẹbun Oloyede, tawọn eeyan mọ si Ọlaiya Igwe, ba yi orukọ rẹ pada si Eebudọla lasiko yii, ọkunrin naa ko jayo pa, tori nnkan aritọkasi ati ẹbun nla ni eebu tawọn eeyan bu u laipẹ yii mu ba a, bi ko ba si yi orukọ ẹ, Ẹbun, pada, a jẹ pe orukọ naa n ro o, orukọ ọhun si n ko oriire ba a gidigidi ni, tori bo ṣe n fọwọ ọtun gba ẹbun nla, bẹẹ ni wọn n ta a lọrẹ lọwọ osi.
Eyi ko ṣẹyin bi Alaga igbimọ to n ṣamojuto awọn ibudokọ ero l’Ekoo (Lagos State Park and Garages Management), Alaaji Musiliu Akinsanya, tawọn eeyan mọ si MC Oluọmọ, ṣe tun fi ẹbun ilẹ pulọọti kan ta Ọlaiya Igwe lọrẹ, latari bawọn eeyan ṣe bu u, ti wọn si ṣaata rẹ fun bi onitiata naa ṣe n yiraa nilẹ, to dọbalẹ, to si n ṣapẹ fun MC Oluọmọ nigba tiyẹn fun un lẹbun ọkọ ayọkẹlẹ jiipu bọginni pe ko fi ṣayẹyẹ ọjọọbi ẹ lọsẹ kan aabọ sẹyin.
Tẹ o ba gbagbe, ileeṣẹ tẹlifiṣan Alaroye mu iroyin iṣẹlẹ naa wa fun yin tẹlẹ, nigba ti idunnu ṣubu lu ayọ fun Ọlaiya, ti wọn fun un lọkọ ayọkẹlẹ naa, eyi si waye lẹyin ti ọkan lara awọn ololufẹ rẹ sọko ọrọ si i lori foonu latilu oyinbo, fun bi ọkunrin naa ṣe n ṣe kurukẹrẹ lẹyin MC Oluọmọ. Iyẹn bu u pe ko ri ere kan mu bọ latọjọ to ti n tẹle ọga awọn ọlọkọ ọhun.
Boya eyi lo mu ki ẹbun ọkọ ayọkẹlẹ tuntun naa tẹ ẹ lọwọ, amọ, eebu mi-in lawọn eeyan tun bu u lori bo ṣe fi ẹmi imoore ẹ han, wọn ni ẹgbẹ aburo rẹ lo n yiraa nilẹ fun, wọn ni adiẹ funfun rẹ ko mọra ẹ lagba rara.
Ọlaiya naa fesi o, o ni kawọn eeyan gbẹnu dakẹ jare, ewo lo tiẹ kan wọn gan-an ninu bi oun ṣe dupẹ fun ẹbun ti wọn foun, bawo ni alara aa ṣe lara ko ro oun tawọn eeyan yoo si maa ki tọhun kuu aisun, kuu aiwo, o loun loun lara oun toun gbe yilẹ, bo ba si ṣe wu ọlọpẹ lo le dupẹ ẹ, ko kan aye rara, ati pe gbogbo ẹgan ati eebu wọnyi, tọtun-un tosi lẹyẹle toun fi n kore wọle ni o, oun o ri tẹnikan ro rara.
Ṣa, eebu ti dọla fun Igwe o, wọn bu u, o gba mọto, wọn tun bu u, o donilẹ l’Ekoo, lọla MC Oluọmọ.