Lẹyin oṣu kan aabọ, awọn oṣiṣẹ kootu ipinlẹ Ogun fagi le iyanṣẹlodi

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Iyanṣẹlodi ti awọn oṣiṣẹ kootu ipinlẹ Ogun bẹrẹ lọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ, ọdun 2021 yii, ti wa sopin bayii. Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu kẹsan-an, ni wọn fagi le e lẹyin ipade to waye laarin awọn aṣoju eto idajọ ati ijọba ipinlẹ Ogun.

Oke-Mosan nipade ọhun ti waye l’Ọjọbọ, Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Tokunbọ Talabi ati Olori awọn oṣiṣẹ Ogun, Abilekọ Sẹlimọt Ọttun, lo gbalejo Alaga awọn oṣiṣẹ eto idajọ nipinlẹ yii, Tajudeen Ẹdun. Lẹyin ipade naa ni wọn si kede pe iyanṣẹlodi naa ti dopin, ki kaluku pada sẹnu iṣẹ ẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ọdun 2021.

Nigba to n ṣalaye fawọn akọroyin lẹyin ipade naa, Ọgbẹni Ẹdun sọ pe ọpọlọpọ ipade lo ti waye laarin ajọ eleto idajọ ati ijọba ipinlẹ Ogun, ko too di pe awọn pada ri i sọ bayii.

“Ọrọ lori owo-oṣu wa tijọba n ge ku la sọ, a ti sọ ohun ti a fẹ, ijọba naa si ti sọ tiwọn, a si ti fẹnu ko, iyanṣẹlodi naa ti dopin” Bẹẹ ni Alaga awọn oṣiṣẹ kootu nipinlẹ Ogun yii wi.

Ẹ oo ranti pe lẹyin ti awọn oṣiṣẹ kootu kaakiri orilẹ-ede yii (JUSUN) wọle iyanṣẹlodi wọn ni ipinlẹ Ogun bẹrẹ tiẹ, latari owo-oṣu wọn ti wọn ni ijọba ko san pe.

Leave a Reply