Iroyin ayọ lo jẹ fun gbogbo awọn akẹkọọ ati obi to ni ọmọ ni awọn ileewe giga fasiti kaakiri ilẹ wa nigba ti wọn gbọ pe ẹgbẹ awọn olukọ ileewe giga fasiti yii, Academic Staff Union of University (ASUU), ti fopin si iyanṣẹlodi ti wọn ti n ṣe lati bii oṣu mẹsan-an sẹyin.
Alaga ẹgbẹ awọn olukọ naa, Ọjọgbọn Biọdun Ogunyẹmi, lo kede ọrọ naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ niluu Abuja. O ni igbesẹ yii waye lẹyin ti awọn jọ fikun lukun pẹlu igbimọ apaṣẹ ilẹ wa, iyẹn National Executive Council.
Ọkunrin naa ni ọpọ ibeere awọn ni ijọba ti dahun si, ti wọn si tun ṣeleri lati ṣiṣẹ lori awọn eyi to ku laipẹ jọjọ.
Nidii eyi, lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni ni awọn ti fopin si iyanṣẹlodi naa.
Tẹ o ba gbagbe, lati inu oṣu kẹta, ọdun yii ni iyanṣẹlodi naa ti bẹrẹ, ti ọpọ ipade ti wọn ṣe pẹlu ijọba si fori sanpọn ko too waa di pe agbọye wa laarin wọn bayii.