Lẹyin oṣu mẹsan-an ti Iya Tadenikawo ko jade laafin, Ọọni Ogunwusi tẹwọ gba Olori Mariam

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Olori tuntun, Mariam Anako, la gbọ pe o ti gunlẹ si aafin Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, bayii.

 

Alẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ni awọn mọlẹbi Ọba Ogunwusi lọọ mu olori tuntun naa wa lati ilu Ilọrin ti awọn mọlẹbi rẹ wa.

Ọmọ bibi Ẹbira, nipinlẹ Kogi, ni wọn pe olori naa, ilu Ẹrin-Ile, nipinlẹ Kwara, ni iya rẹ to to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ọlọpaa ti wa.

Ileeṣẹ ipọnpo nla kan la gbọ pe o ti n ṣiṣẹ, ọdọ ọga agba funleeṣẹ ọlọpaa ilẹ yii nigba kan, Dikko Abubakar, la gbọ pe o gbe dagba.

A oo ranti pe inu oṣu Kejila, ọdun to kọja, ni olori tẹlẹ, Naomi Ṣilẹkunọla, ọmọ bibi ilu Akurẹ, ko jade laafin lẹyin to bimọ ọkunrin kan, Tadenikawo, fun kabiesi.

Leave a Reply