Lẹyin oṣu mẹta ti wọn dana sunle ẹ, awọn agbanipa tun ka Sunday Igboho mọle loru

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin oṣu mẹta geere ti awọn òṣìkà ẹda dana sun ile ajafẹtọọ ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ, awọn agbanipa tun ko ọpọlọpọ ibọn atoogun lọọ ka baba ti gbogbo aye mọ sí Sunday Igboho naa mọle, ṣugbọn ori tun ko akinkanju ọkunrin naa yọ.

Ni nnkan bii aago kan aabọ oru mọju ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kẹrin, ọdun 2021 yii, ti i ṣe ọjọ Aje, Mọnde, lawọn ẹruuku ọhun polowo iku lọọ ka a mọle ẹ to wa laduugbo Soka, n’Ibadan, ṣugbọn tọkunrin naa jẹwọ fun wọn pe oun gan-an ni wọn n pe ni iku aye ti i pa iku jẹ gẹgẹ bii ọkan ninu awọn oriki abami ti gbajugbaja onifuji nni, Ọba Orin Saheed Oṣupa fi ki i ninu awo orin rẹ kan.

 

ALAROYE gbọ pe tibọntibọn tooguntoogun lawọn eeyan naa rin, ti wọn si rọjo ibọn bo ile akọni ọkunrin naa bii ki wọn yinbọn pa a mọ mọnu ile nibẹ, ṣugbọn awọn ẹruuku to n ṣọ olugbija iran Yoruba naa jade ti wọn, wọn si jọ dana ibọn funra wọn ya gidigidi ko too di pe awọn ọlọtẹ fori balẹ, ti wọn si juba ehoro.

Laarin bii ọgbọn iṣẹju ti wọn fi yinbọn funra wọn ọhun, ere ọwọ́ lasan la gbọ pe kinni naa jọ loju awọn ọmọ Igboho Ooṣa, ṣugbọn gbogbo adugbo Soka lo mọ pe awọn gbalejo, bii ogun gidi niṣẹlẹ ọhun jọ loju wọn.

Oludamọran fun Sunday Igboho lori eto iroyin, Ọgbẹni Dapọ Salami, fidi ẹ mulẹ fakọroyin wa pe, “Loootọ ni wọn waa ka baba (Igboho) mọle, ṣugbọn a dupẹ pe wọn ko ri erongba wọn mu ṣẹ.

“Ni nnkan bii aago kan aabọ oru ni wọn wa. Mi o le ṣalaye bi wọn ṣe pọ to atawọn nnkan ija ti wọn ko wa, ṣugbọn ohun ti mo le sọ fun yin ni pe wọn ba baba (Igboho) naa gẹgẹ bo ṣe yẹ ki wọn ba akinkanju ọkunrin.

“Ko si nnkan to ṣe baba tabi ẹnikẹni ninu ile wọn.”

Ohun ti awọn ololufẹ ajafẹtọọ Yoruba yii kaakiri agbaye wa n beere, ṣugbọn ti ko ti i si esi gidi fun ibeere ọhun ni pe “awọn wo gan-an ni wọn fẹẹ pa Sunday Igboho”?

 

Leave a Reply