Ọrẹoluwa Adedeji
O da bii pe ẹwọn wu Rilwan Sodiq, ẹni ọdun mejilelogun, ju ko maa gbe lominira lọ nitori ko pẹ to ti ẹwọn de ti awọn ikọ ọlọpaa ayaraṣaṣa (RRS), tun gba a mu lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni agbegbe Abiọla Garden, l’Ọjọta, nibi to ti n ja obinrin kan to wa ninu mọto rẹ lole.
Foonu Samsung Galaxy Note 9 lo gba lọwọ obinrin kan to wa ninu mọto Siena rẹ jẹẹjẹ. Niṣe lọmọkunrin ti wọn jọ n jale, torukọ iyẹn naa n jẹ Sodiq n ba obinrin naa sọrọ, bi Rilwan ṣe nawọ mu foonu obinrin ti wọn pe ni Alaaja yii to wa lẹgbẹẹ rẹ niyi.
Eyi lo mu obinrin naa fariwo bọnu, ọpẹlọpẹ awọn RRS ti wọn wọn wa lodikeji pẹlu awọn eeyan to wa nitosi ti wọn le ọmọkunrin ti ọwọ n dun naa titi ti wọn fi ri i mu ni agbegbe Abiọla Garden, to wa ni Ọjọta.
Inu pata to ki foonu naa si lo ti yọ ọ jade, to si fun awọn ọlọpaa yii.
Rilwan jẹwọ fawọn agbofinro naa pe ninu oṣu Kejila, ọdun to kọja, loun ṣẹṣẹ jade kuro lọgba ẹwọn Kirikiri, ẹsun ole yii kan naa lo gbe oun lọ.
O fi kun un pe awọn mẹta loun ti ja foonu wọn gba laipẹ yii lọna ti oun fi ja ti obinrin yii naa gba.